1 Angẹli tí ó wọ aṣọ funfun náà ní, “Ní àkókò náà Mikaeli, aláṣẹ ńlá, tí ń dáàbò bo àwọn eniyan rẹ, yóo dìde. Àkókò ìyọnu yóo dé, irú èyí tí kò tíì sí rí láti ọjọ́ tí aláyé ti dáyé; ṣugbọn a óo gba gbogbo àwọn eniyan rẹ, tí a bá kọ orúkọ wọn sinu ìwé náà là.
2 Ọ̀pọ̀ ninu àwọn tí ó ti kú, tí wọ́n ti sin ni yóo jí dìde, àwọn kan óo jí sí ìyè ainipẹkun, àwọn mìíràn óo sì jí sí ìtìjú ati ẹ̀sín ainipẹkun.
3 Àwọn ọlọ́gbọ́n yóo máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run, àwọn tí wọn ń yí eniyan pada sí ọ̀nà òdodo yóo máa tàn bí ìràwọ̀ lae ati títí lae.”
4 Ó ní, “Ṣugbọn ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé, kí o sì fi èdìdì dì í títí di àkókò ìkẹyìn. Nítorí àwọn eniyan yóo máa sá síhìn-ín, sá sọ́hùn-ún, ìmọ̀ yóo sì pọ̀ sí i.”