16 Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, kò yẹ kí á máa bá ọ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí.
17 Bí o bá sọ wá sinu iná, Ọlọrun wa tí à ń sìn lè yọ wá ninu adágún iná, ó sì lè gbà wá lọ́wọ́ ìwọ ọba pàápàá.
18 Ṣugbọn bí kò bá tilẹ̀ gbà wá, a fẹ́ kí ọba mọ̀ pé a kò ní fi orí balẹ̀, kí á sin ère wúrà tí ó gbé kalẹ̀.”
19 Inú bá bí Nebukadinesari gidigidi, ojú rẹ̀ yipada sí Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n dá iná, kí ó gbóná ní ìlọ́po meje ju bíí tií máa ń gbóná tẹ́lẹ̀ lọ.
20 Ó tún pàṣẹ pé kí àwọn akọni ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ di Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, kí wọ́n sì sọ wọ́n sinu adágún iná.
21 Wọ́n di àwọn mẹtẹẹta pẹlu agbádá, ati aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀, ati fìlà wọn, ati àwọn aṣọ wọn mìíràn, wọ́n sì sọ wọ́n sí ààrin adágún iná tí ń jó.
22 Nítorí bí àṣẹ ọba ti le tó, ati bí adágún iná náà ti gbóná tó, ahọ́n iná tí ń jó bùlàbùlà jó àwọn tí wọ́n gbé Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego sinu rẹ̀ ní àjópa.