Daniẹli 3:21-27 BM

21 Wọ́n di àwọn mẹtẹẹta pẹlu agbádá, ati aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀, ati fìlà wọn, ati àwọn aṣọ wọn mìíràn, wọ́n sì sọ wọ́n sí ààrin adágún iná tí ń jó.

22 Nítorí bí àṣẹ ọba ti le tó, ati bí adágún iná náà ti gbóná tó, ahọ́n iná tí ń jó bùlàbùlà jó àwọn tí wọ́n gbé Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego sinu rẹ̀ ní àjópa.

23 Nítorí dídì tí wọ́n di Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, wọ́n ṣubú lulẹ̀ sí ààrin iná náà.

24 Lójijì Nebukadinesari ta gìrì, ó sáré dìde, ó sì bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé, “Ṣebí eniyan mẹta ni a dì, tí a gbé sọ sinu iná?”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kabiyesi.”

25 Ó ní, “Ẹ wò ó, eniyan mẹrin ni mo rí yìí, wọ́n wà ní títú sílẹ̀, wọ́n ń rìn káàkiri láàrin iná, iná kò sì jó wọn, Ìrísí ẹni kẹrin dàbí ti ẹ̀dá ọ̀run.”

26 Nebukadinesari ọba bá lọ sí ẹnu ọ̀nà adágún iná náà, ó kígbe pé, “Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, ẹ̀yin iranṣẹ Ọlọrun alààyè, ẹ jáde wá!” Wọ́n bá jáde kúrò ninu iná lẹsẹkẹsẹ.

27 Gbogbo àwọn baálẹ̀ ìgbèríko, àwọn olórí, àwọn gomina, ati àwọn ìgbìmọ̀ ọba, kó ara wọn jọ, wọ́n sì rí i pé iná kò jó àwọn ọkunrin wọnyi, irun orí wọn kò rùn, ẹ̀wù wọn kò yipada, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tilẹ̀ gbóòórùn iná lára wọn.