24 “Kabiyesi, ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: Àṣẹ tí Ẹni Gíga Jùlọ pa nípa oluwa mi, ọba ni.
25 A óo lé ọ jáde kúrò láàrin àwọn eniyan, o óo sì máa bá àwọn ẹranko inú igbó gbé; o óo máa jẹ koríko bíi mààlúù, ìrì yóo sì sẹ̀ sí ọ lára fún ọdún meje, títí tí o óo fi mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹni tí ó bá wù ú níí sì í gbé e lé lọ́wọ́.
26 Olùṣọ́ náà pàṣẹ pé kí á fi gbòǹgbò igi náà sílẹ̀ ninu ilẹ̀; ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, dájúdájú, o óo tún pada wá jọba, nígbà tí o bá gbà pé Ọlọrun ni ọba gbogbo ayé.
27 Nítorí náà, kabiyesi, gba ìmọ̀ràn tí n óo fún ọ yìí; jáwọ́ ninu ẹ̀ṣẹ̀, sì máa ṣe òdodo, jáwọ́ ninu ìwà ìkà, máa ṣàánú fún àwọn tí a ni lára, bóyá èyí lè mú kí àkókò alaafia rẹ gùn sí i.”
28 Gbogbo nǹkan wọnyi sì ṣẹ mọ́ Nebukadinesari ọba lára.
29 Ní ìparí oṣù kejila, bí ó ti ń rìn lórí òrùlé ààfin Babiloni,
30 ó ní, “Ẹ wo bí Babiloni ti tóbi tó, ìlú tí mo fi ipá ati agbára mi kọ́, tí mo sọ di olú-ìlú fún ògo ati ọlá ńlá mi.”