28 Gbogbo nǹkan wọnyi sì ṣẹ mọ́ Nebukadinesari ọba lára.
29 Ní ìparí oṣù kejila, bí ó ti ń rìn lórí òrùlé ààfin Babiloni,
30 ó ní, “Ẹ wo bí Babiloni ti tóbi tó, ìlú tí mo fi ipá ati agbára mi kọ́, tí mo sọ di olú-ìlú fún ògo ati ọlá ńlá mi.”
31 Kí ó tó wí bẹ́ẹ̀ tán, ẹnìkan fọhùn láti ọ̀run, ó ní, “Nebukadinesari ọba, gbọ́ ohun tí a ti pinnu nípa rẹ: a ti gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ rẹ,
32 a óo lé ọ kúrò láàrin àwọn eniyan, o óo máa bá àwọn ẹranko gbé, o óo sì máa jẹ koríko bíi mààlúù fún ọdún meje, títí tí o óo fi mọ̀ pé, Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ati pé ẹni tí ó bá wù ú ní í máa gbé e lé lọ́wọ́.”
33 Lẹsẹkẹsẹ ni ọ̀rọ̀ náà ṣẹ mọ́ Nebukadinesari lára. Wọ́n lé e kúrò láàrin àwọn eniyan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko bíi mààlúù. Ìrì sẹ̀ sí i lára títí tí irun orí rẹ̀ fi gùn bí ìyẹ́ idì, èékánná rẹ̀ sì dàbí ti ẹyẹ.
34 Nebukadinesari ní, “Lẹ́yìn ọdún meje náà, èmi, Nebukadinesari, gbé ojú sí òkè ọ̀run, iyè mi pada bọ̀ sípò. Mo yin Ẹni Gíga Jùlọ, mo fi ọlá ati ògo fún Ẹni Ayérayé.“Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ̀láti ìrandíran ni ìjọba rẹ̀,àní, láti ìrandíran ni ìjọba rẹ̀.