6 Nítorí náà, mo pàṣẹ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Babiloni wá sọ́dọ̀ mi, kí wọ́n wá túmọ̀ àlá náà fún mi.
7 Gbogbo àwọn pidánpidán, ati àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea, ati àwọn awòràwọ̀ bá péjọ siwaju mi; mo rọ́ àlá náà fún wọn, ṣugbọn wọn kò lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi.
8 Lẹ́yìn gbogbo wọn patapata ni Daniẹli dé, tí a sọ ní Beteṣasari, orúkọ oriṣa mi, Daniẹli yìí ní ẹ̀mí Ọlọrun ninu. Mo rọ́ àlá mi fún un, mo ní:
9 Beteṣasari, olórí gbogbo àwọn pidánpidán, mo mọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọrun mímọ́ wà ninu rẹ, ati pé o mọ gbogbo àṣírí. Gbọ́ àlá mi kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.
10 “Nígbà tí mo sùn, mo rí igi kan láàrin ayé, lójú ìran, igi náà ga lọpọlọpọ.
11 Igi náà bẹ̀rẹ̀ sí tóbi, ó sì lágbára; orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run, kò sí ibi tí wọn kò ti lè rí i ní gbogbo ayé.
12 Ewé rẹ̀ lẹ́wà, ó so jìnwìnnì, oúnjẹ wà lórí rẹ̀ fún gbogbo eniyan, abẹ́ rẹ̀ ni àwọn ẹranko ń gbé, orí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ni àwọn ẹyẹ ń sùn. Èso rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀dá alààyè ń jẹ.