Daniẹli 5:16-22 BM

16 Mo ti gbọ́ nípa rẹ pé o lè túmọ̀ ohun ìjìnlẹ̀, o sì lè yanjú ọ̀rọ̀ tí ó bá díjú; nisinsinyii, bí o bá lè ka àkọsílẹ̀ yìí, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, wọn óo wọ̀ ọ́ ní aṣọ elése àlùkò, wọn óo sì fi ẹ̀gbà wúrà sí ọ lọ́rùn, o óo sì wà ní ipò kẹta sí ọba ní ìjọba mi.”

17 Daniẹli dá ọba lóhùn, ó ní, “Jẹ́ kí ẹ̀bùn rẹ máa gbé ọwọ́ rẹ, kí o sì fi ọrẹ rẹ fún ẹlòmíràn. Ṣugbọn n óo ka àkọsílẹ̀ náà fún ọba, n óo sì túmọ̀ rẹ̀.

18 “Kabiyesi, Ọlọrun tí ó ga jùlọ fún Nebukadinesari, baba rẹ ní ìjọba, ó sọ ọ́ di ẹni ńlá, ó fún un ní ògo ati ọlá.

19 Nítorí pé Ọlọrun sọ ọ́ di ẹni ńlá, gbogbo eniyan, gbogbo orílẹ̀-èdè ati gbogbo ẹ̀yà ń tẹríba fún un tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. A máa pa ẹni tí ó bá fẹ́, a sì máa dá ẹni tí ó fẹ́ sí. A máa gbé ẹni tí ó bá fẹ́ ga, a sì máa rẹ ẹni tí ó bá wù ú sílẹ̀.

20 Ṣugbọn nígbà tí ó gbé ara rẹ̀ ga, tí ó sì ṣe oríkunkun, a mú un kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, a sì mú ògo rẹ̀ kúrò.

21 A lé e kúrò láàrin àwọn ọmọ eniyan, ọkàn rẹ̀ dàbí ti ẹranko. Ó ń bá àwọn ẹranko gbé inú igbó. Ó ń jẹ koríko bíi mààlúù, ìrì sì sẹ̀ sí i lára, títí ó fi mọ̀ pé Ọlọrun tí ó ga jùlọ, ni ó ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, tí ó sì ń gbé e fún ẹni tí ó bá wù ú.

22 “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ ọmọ rẹ̀ Beṣasari, o kọ̀, o kò rẹ ara rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.