6 Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ìhà gúsù, ó sì ń yípo lọ sí ìhà àríwá. Yíyípo ni afẹ́fẹ́ ń yípo, a sì tún pada sí ibi tí ó ti wá.
7 Inú òkun ni gbogbo odò tí ń ṣàn ń lọ, ṣugbọn òkun kò kún. Ibi tí àwọn odò ti ń ṣàn wá, ibẹ̀ ni wọ́n tún ṣàn pada lọ.
8 Gbogbo nǹkan ní ń kó àárẹ̀ bá eniyan, ju bí ẹnu ti lè sọ lọ. Ìran kì í sú ojú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ kì í kún etí.
9 Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóo máa wà. Ohun tí a ti ṣe tẹ́lẹ̀ náà ni a óo tún máa ṣe, kò sí ohun titun kan ní ilé ayé.
10 Ǹjẹ́ ohun kankan wà tí a lè tọ́ka sí pé: “Wò ó! Ohun titun nìyí.” Ó ti wà rí ní ìgbà àtijọ́.
11 Kò sí ẹni tí ó ranti àwọn nǹkan àtijọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni, kò sì ní sí ẹni tí yóo ranti àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la.
12 Èmi ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ti jẹ ọba lórí Israẹli, ní Jerusalẹmu.