Ìwé Oníwàásù 5 BM

Ronú Wò Kí O tó Ṣèlérí

1 Ṣọ́ra, nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọrun, ó sàn kí o lọ máa kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ ju pé kí o lọ máa rúbọ bí àwọn aṣiwèrè tí ń ṣe, tí wọn kò sì mọ̀ pé nǹkan burúkú ni àwọn ń ṣe.

2 Má fi ẹnu rẹ sọ ìsọkúsọ, má sì kánjú sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọrun, nítorí Ọlọrun ń bẹ lọ́run ìwọ sì wà láyé, nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ níwọ̀n.

3 Ọpọlọpọ àkóléyà ní ń mú kí eniyan máa lá àlákálàá, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ni eniyan sì fi ń mọ òmùgọ̀.

4 Bí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Ọlọrun, má fi falẹ̀, tètè san án, nítorí kò ní inú dídùn sí àwọn òmùgọ̀.

5 Ó sàn kí o má jẹ́ ẹ̀jẹ́ rárá ju pé kí o jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí o má mú un ṣẹ lọ.

6 Má jẹ́ kí ẹnu rẹ mú ọ dẹ́ṣẹ̀, kí o má baà lọ máa yí ohùn pada lọ́dọ̀ iranṣẹ Ọlọrun pé, èèṣì ló ṣe. Má jẹ́ kí Ọlọrun bínú sí ọ, kí ó má baà pa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ run.

7 Nígbà tí àlá bá pọ̀ ọ̀rọ̀ náà yóo pọ̀. Ṣugbọn pataki ni pé, ǹjẹ́ o tilẹ̀ bẹ̀rù Ọlọrun?

Asán Ni Ayé

8 Bí o bá wà ní agbègbè tí wọ́n ti ń pọ́n talaka lójú, tí kò sì sí ìdájọ́ òdodo ati ẹ̀tọ́, má jẹ́ kí èyí yà ọ́ lẹ́nu. Nítorí ẹni tí ó ga ju ọ̀gá àgbà lọ ń ṣọ́ ọ̀gá àgbà. Ẹni tó tún ga ju àwọn náà lọ tún ń ṣọ́ gbogbo wọn.

9 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, anfaani ni ilẹ̀ tí à ń dáko sí jẹ́ fún ọba.

10 Kò sí iye tó lè tẹ́ ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó lọ́rùn; bákan náà ni ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọrọ̀, kò sí iye tí ó lè jẹ lérè tí yóo tẹ́ ẹ lọ́rùn. Asán ni èyí pẹlu.

11 Bí ọrọ̀ bá ti ń pọ̀ sí, bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn tí yóo máa lò ó yóo máa pọ̀ sí i. Kò sì sí èrè tí ọlọ́rọ̀ yìí ní ju pé ó fi ojú rí ọrọ̀ rẹ̀ lọ.

12 Oorun dídùn ni oorun alágbàṣe, kì báà yó, kì báà má yó; ṣugbọn ìrònú ọrọ̀ kì í jẹ́ kí ọlọ́rọ̀ sùn lóru.

13 Nǹkankan ń ṣẹlẹ̀, tí ó burú, tí mo ṣàkíyèsí láyé yìí, àwọn eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ fún ìpalára ara wọn.

14 Àdáwọ́lé wọn lè yí wọn lọ́wọ́, wọ́n sì lè fi bẹ́ẹ̀ pàdánù ọrọ̀ wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè rí nǹkankan fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn.

15 Bí eniyan ti wáyé níhòòhò láìmú nǹkankan lọ́wọ́ wá bẹ́ẹ̀ ni yóo pada, láìmú nǹkankan lọ́wọ́ lọ, bí èrè làálàá tí a ṣe láyé.

16 Nǹkan burúkú gan-an ni èyí pàápàá jẹ́; pé bí a ṣe wá bẹ́ẹ̀ ni a óo ṣe lọ. Tabi èrè wo ni ó wà ninu pé asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo làálàá wa láyé.

17 Ninu òkùnkùn, ati ìbànújẹ́ ni a ti ń lo ìgbésí ayé wa, pẹlu ọpọlọpọ ìyọnu, àìsàn ati ibinu.

18 Wò ó! Ohun tí mo rí pé ó dára jù, tí ó sì yẹ, ni pé kí eniyan jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn gbogbo làálàá tí ó ń ṣe láyé, ní ìwọ̀nba ọjọ́ tí Ọlọrun fún un, nítorí èyí ni ìpín rẹ̀.

19 Gbogbo ẹni tí Ọlọrun bá fún ní ọrọ̀ ati ohun ìní, ati agbára láti gbádùn wọn, ati láti gba ìpín rẹ̀ kí ó sì láyọ̀ ninu iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ẹ̀bùn Ọlọrun ni.

20 Kò ní ranti iye ọjọ́ ayé rẹ̀ nítorí pé, Ọlọrun ti fi ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12