Ìwé Oníwàásù 4 BM

1 Mo tún rí i bí àwọn eniyan tí ń ni ẹlòmíràn lára láyé.Wò ó! Omi ń bọ́ lójú àwọn tí à ń ni lára,Kò sì sí ẹnìkan tí yóo tù wọ́n ninu.Ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára ni agbára kọ̀dí sí,kò sì sí ẹni tí yóo tu àwọn tí à ń ni lára ninu.

2 Mo wá rò ó pé, àwọn òkú, tí wọ́n ti kú,ṣe oríire ju àwọn alààyè tí wọ́n ṣì wà láàyè lọ.

3 Ṣugbọn ti ẹni tí wọn kò tíì bí rárá,sàn ju ti àwọn mejeeji lọ,nítorí kò tíì rí iṣẹ́ ibití àwọn ọmọ aráyé ń ṣe.

4 Mo rí i pé gbogbo làálàá tí eniyan ń ṣe ati gbogbo akitiyan rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, ó ń ṣe é nítorí pé eniyan ń jowú aládùúgbò rẹ̀ ni. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pàápàá.

5 Òmùgọ̀ eniyan níí káwọ́ gbera,tíí fi ebi pa ara rẹ̀ dójú ikú.

6 Ó sàn kí eniyan ní nǹkan díẹ̀ pẹlu ìbàlẹ̀ àyàju pé kí ó ní ọpọlọpọ, pẹlu làálàá ati ìmúlẹ̀mófo lọ.

7 Mo tún rí ohun asán kan láyé:

8 Ọkunrin kan wà tí kò ní ẹnìkan,kò lọ́mọ, kò lárá, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìyekan,sibẹsibẹ làálàá rẹ̀ kò lópin,bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìtẹ́lọ́rùn ninu ọrọ̀ rẹ̀.Kò fijọ́ kan bi ara rẹ̀ léèrè rí pé, “Ta ni mò ń ṣe làálàá yìí fúntí mo sì ń fi ìgbádùn du ara mi?”Asán ni èyí pàápàá ati ìmúlẹ̀mófo.

9 Eniyan meji sàn ju ẹnìkan ṣoṣo lọ,nítorí wọn yóo lè jọ ṣiṣẹ́,èrè wọn yóo sì pọ̀.

10 Bí ọ̀kan bá ṣubú,ekeji yóo gbé e dìde.Ṣugbọn ẹni tí ó dá wà gbé!Nítorí nígbà tí ó bá ṣubúkò ní sí ẹni tí yóo gbé e dìde.

11 Bẹ́ẹ̀ sì tún ni, bí eniyan meji bá sùn pọ̀,wọn yóo fi ooru mú ara wọnṣugbọn báwo ni ẹnìkan ṣe lè fi ooru mú ara rẹ̀?

12 Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ni eniyan kan lè dojú ìjà kọ,nítorí pé eniyan meji lè gba ara wọn kalẹ̀.Okùn onípọn mẹta kò lè ṣe é já bọ̀rọ̀.

13 Ọlọ́gbọ́n ọdọmọde tí ó jẹ́ talaka, sàn ju òmùgọ̀ àgbàlagbà ọba, tí kò jẹ́ gba ìmọ̀ràn lọ,

14 kì báà jẹ́ pé láti ọgbà ẹ̀wọ̀n ni òmùgọ̀ ọba náà ti bọ́ sórí ìtẹ́, tabi pé láti inú ìran talaka ni a ti bí i.

15 Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn kiri láyé ati ọdọmọde náà tí yóo gba ipò ọba.

16 Àwọn eniyan tí ó jọba lé lórí pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní òǹkà; sibẹ, àwọn ìran tí ó bá dé lẹ́yìn kò ní máa yọ̀ nítorí rẹ̀. Dájúdájú asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12