Ìwé Oníwàásù 10 BM

1 Bí òkú eṣinṣin ṣe lè ba òórùn turari jẹ́;bẹ́ẹ̀ ni ìwà òmùgọ̀ kékeré lè ba ọgbọ́n ńlá ati iyì jẹ́.

2 Ọkàn ọlọ́gbọ́n eniyan a máa darí rẹ̀ sí ọ̀nà rere,ṣugbọn ọ̀nà burúkú ni ọkàn òmùgọ̀ ń darí rẹ̀ sí.

3 Ìrìn ẹsẹ̀ òmùgọ̀ láàrin ìgboro ń fihàn pé kò gbọ́n,a sì máa fihan gbogbo eniyan bí ó ti gọ̀ tó.

4 Bí aláṣẹ bá ń bínú sí ọ,má ṣe torí rẹ̀ kúrò ní ìdí iṣẹ́ rẹ,ìtẹríba lè mú kí wọn dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó bá tóbi jini.

5 Nǹkan burúkú tí mo tún rí láyé ni, irú àṣìṣe tí àwọn aláṣẹ pàápàá ń ṣe:

6 Wọ́n fi àwọn òmùgọ̀ sí ipò gíga, nígbà tí àwọn ọlọ́rọ̀ wà ní ipò tí ó rẹlẹ̀.

7 Mo rí i tí àwọn ẹrú ń gun ẹṣin, nígbà tí àwọn ọmọ-aládé ń fẹsẹ̀ rìn bí ẹrú.

8 Ẹni tí ó gbẹ́ kòtò ni yóo jìn sinu rẹ̀,ẹni tí ó bá já ọgbà wọlé ni ejò yóo bùjẹ.

9 Ẹni tí ó bá ń fọ́ òkúta, ni òkúta í pa lára;ẹni tí ó bá ń la igi, ni igi í ṣe ní jamba.

10 Ẹni tí kò bá pọ́n àáké rẹ̀ kí ó mú,yóo lo agbára pupọ bí ó bá fẹ́ lò ó,ṣugbọn ọgbọ́n a máa ranni lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí.

11 Lẹ́yìn tí ejò bá ti buni jẹ tán,kò ṣàǹfààní mọ́ kí á máa pọfọ̀ sí ejò.

12 Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa bu iyì kún un,ṣugbọn ẹnu òmùgọ̀ ni yóo pa á.

13 Agọ̀ ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀,wèrè sì ni ìparí rẹ̀.

14 Òmùgọ̀ ń sọ̀rọ̀ láìdákẹ́,kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ń bọ̀ lẹ́yìn ọ̀la,ta ni lè sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ fún un.

15 Làálàá ọ̀lẹ ń kó àárẹ̀ bá a,tóbẹ́ẹ̀ tí kò mọ ọ̀nà ìlú mọ́.

16 Ilẹ̀ tí ọba rẹ̀ jẹ́ ọmọde gbé!Tí àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe àríyá láàárọ̀.

17 Ilẹ̀ tí ọba rẹ̀ kì í bá ṣe ọmọ ẹrú ṣoríire!Tí àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe àríyá ní àsìkò tí ó tọ́;tí wọn ń jẹ tí wọn ń mu kí wọn lè lágbára,ṣugbọn tí kì í ṣe fún ìmutípara.

18 Ọ̀lẹ a máa jẹ́ kí ilé ẹni wó,ìmẹ́lẹ́ a máa jẹ́ kí ilé ẹni jò.

19 Oúnjẹ a máa múni rẹ́rìn-ín,waini a sì máa mú inú ẹni dùn,ṣugbọn owó ni ìdáhùn ohun gbogbo.

20 Má bú ọba, kì báà jẹ́ ninu ọkàn rẹ,má sì gbé ọlọ́rọ̀ ṣépè, kì báà jẹ́ ninu yàrá rẹ,nítorí atẹ́gùn lè gbé ọ̀rọ̀ rẹ lọ,tabi kí àwọn ẹyẹ kan lọ ṣòfófó rẹ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12