1 Gbogbo nǹkan láyé yìí ló ní àkókò ati ìgbà tirẹ̀:
2 àkókò bíbí wà, àkókò kíkú sì wà;àkókò gbígbìn wà, àkókò kíkórè ohun tí a gbìn sì wà.
3 Àkókò pípa wà, àkókò wíwòsàn sì wà,àkókò wíwó lulẹ̀ wà, àkókò kíkọ́ sì wà.
4 Àkókò ẹkún wà, àkókò ẹ̀rín sì wà;àkókò ọ̀fọ̀ wà, àkókò ijó sì wà.
5 Àkókò fífọ́n òkúta ká wà, àkókò kíkó òkúta jọ sì wà;àkókò ìkónimọ́ra wà, àkókò àìkónimọ́ra sì wà.