7 Àkókò fífa nǹkan ya wà, àkókò rírán nǹkan pọ̀ sì wà;àkókò dídákẹ́ wà, àkókò ọ̀rọ̀ sísọ sì wà.
8 Àkókò láti fi ìfẹ́ hàn wà àkókò láti kórìíra sì wà;àkókò ogun wà, àkókò alaafia sì wà.
9 Kí ni èrè làálàá òṣìṣẹ́?
10 Mo ti mọ ẹrù ńlá tí Ọlọrun dì ru ọmọ eniyan.
11 Ó ṣe ohun gbogbo dáradára, ní àkókò rẹ̀. Ó fi ayérayé sí ọkàn eniyan, sibẹ, ẹnikẹ́ni kò lè rídìí ohun tí Ọlọrun ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.
12 Mo mọ̀ pé kò sí ohun tí ó yẹ wọ́n ju pé kí inú wọn máa dùn, kí wọ́n sì máa ṣe rere ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn;
13 ati pé ẹ̀bùn Ọlọrun ni pé kí olukuluku jẹ, kí ó mu, kí ó sì gbádùn lẹ́yìn làálàá rẹ̀.