9 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, anfaani ni ilẹ̀ tí à ń dáko sí jẹ́ fún ọba.
10 Kò sí iye tó lè tẹ́ ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó lọ́rùn; bákan náà ni ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọrọ̀, kò sí iye tí ó lè jẹ lérè tí yóo tẹ́ ẹ lọ́rùn. Asán ni èyí pẹlu.
11 Bí ọrọ̀ bá ti ń pọ̀ sí, bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn tí yóo máa lò ó yóo máa pọ̀ sí i. Kò sì sí èrè tí ọlọ́rọ̀ yìí ní ju pé ó fi ojú rí ọrọ̀ rẹ̀ lọ.
12 Oorun dídùn ni oorun alágbàṣe, kì báà yó, kì báà má yó; ṣugbọn ìrònú ọrọ̀ kì í jẹ́ kí ọlọ́rọ̀ sùn lóru.
13 Nǹkankan ń ṣẹlẹ̀, tí ó burú, tí mo ṣàkíyèsí láyé yìí, àwọn eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ fún ìpalára ara wọn.
14 Àdáwọ́lé wọn lè yí wọn lọ́wọ́, wọ́n sì lè fi bẹ́ẹ̀ pàdánù ọrọ̀ wọn, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè rí nǹkankan fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn.
15 Bí eniyan ti wáyé níhòòhò láìmú nǹkankan lọ́wọ́ wá bẹ́ẹ̀ ni yóo pada, láìmú nǹkankan lọ́wọ́ lọ, bí èrè làálàá tí a ṣe láyé.