8 Kí ni anfaani tí ọlọ́gbọ́n ní tí ó fi ju òmùgọ̀ lọ? Kí sì ni anfaani tí talaka rí ninu pé ó mọ̀ ọ́n ṣe ní àwùjọ eniyan.
9 Ó sàn kí ojú ẹni rí nǹkan, ju kí á máa fi ọkàn lépa rẹ̀ lọ. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pẹlu.
10 Ohunkohun tí ó bá ti wà, ó ti ní orúkọ tẹ́lẹ̀, a sì ti mọ ẹ̀dá eniyan, pé eniyan kò lè bá ẹni tí ó lágbára jù ú lọ jà.
11 Asán a máa pọ̀ ninu ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀; kì í sì í ṣe eniyan ní anfaani.
12 Ta ni ó mọ ohun tí ó dára fún eniyan láàrin ìgbà kúkúrú, tí kò ní ìtumọ̀, tí ó níí gbé láyé, àkókò tí ó dàbí òjìji tí ó ń kọjá lọ. Ta ló mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ láyé lẹ́yìn òun, lẹ́yìn tí ó bá ti kú tán?