12 Kò sí ẹni tí ó mọ àkókò tirẹ̀. Bíi kí ẹja kó sinu àwọ̀n burúkú, tabi kí ẹyẹ kó sinu pańpẹ́, ni tàkúté ibi ṣe máa ń mú eniyan, nígbà tí àkókò ibi bá dé bá wọn.
13 Mo tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n kan nílé ayé, ó sì jẹ́ ohun ribiribi lójú mi.
14 Ìlú kékeré kan wà, tí eniyan kò pọ̀ ninu rẹ̀, ọba ńlá kan wà, ó dótì í, ó sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀.
15 Ọkunrin ọlọ́gbọ́n kan wà níbẹ̀ tí ó jẹ́ talaka, ó gba ìlú náà sílẹ̀ pẹlu ọgbọ́n rẹ̀, ṣugbọn ẹnìkan kò ranti talaka náà mọ́.
16 Sibẹsibẹ, mo rí i pé ọgbọ́n ju agbára lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ka ọgbọ́n ọkunrin yìí kún, tí kò sì sí ẹni tí ó fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
17 Ọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ tí ọlọ́gbọ́n bá sọ, ó dára ju igbe aláṣẹ láàrin àwọn òmùgọ̀ lọ.
18 Ọgbọ́n dára ju ohun ìjà ogun lọ, ṣugbọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kanṣoṣo a máa ba nǹkan ribiribi jẹ́.