Joẹli 2:17-23 BM

17 Kí àwọn alufaa, àwọn iranṣẹ Ọlọrun, sọkún láàrin ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ati pẹpẹ ìrúbọ.Kí wọ́n wí pé “OLUWA, dá àwọn eniyan rẹ sí,má sì sọ ilẹ̀ rẹ di ohun ẹ̀gàn ati ohun ẹ̀sín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.Má jẹ́ kí àwọn eniyan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù bèèrè pé,‘Níbo ni Ọlọrun wọn wà?’ ”

18 Nígbà náà ni ara bẹ̀rẹ̀ sí ta OLUWA nítorí ilẹ̀ rẹ̀,ó sì ṣàánú fún àwọn eniyan rẹ̀.

19 OLUWA dá àwọn eniyan rẹ̀ lóhùn pé,“Wò ó! N óo fun yín ní ọkà, waini ati òróró,ẹ óo ní ànítẹ́rùn.N kò ní sọ yín di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́.

20 N óo kó àwọn eṣú láti ìhà àríwá jìnnà kúrò lọ́dọ̀ yín,n óo lé wọn lọ sinu aṣálẹ̀ níbi tí kò sí nǹkankan.N óo lé àwọn tí wọ́n wà níwájú lọ sí inú òkun, ní apá ìlà oòrùn,n óo sì lé àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn lọ sí inú òkun, ní apá ìwọ̀ oòrùn.Òkú wọn yóo máa rùn;n óo pa wọ́n run nítorí ibi ńlá tí wọ́n ṣe.

21 Má bẹ̀rù, ìwọ ilẹ̀,jẹ́ kí inú rẹ máa dùn,kí o sì máa yọ̀,nítorí OLUWA ti ṣe nǹkan ńlá.

22 Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ẹranko inú igbó,nítorí ewéko gbogbo ni ó tutù,igi gbogbo ti so èso,igi ọ̀pọ̀tọ́ ati ọgbà àjàrà sì ti so jìnwìnnì.

23 “Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni,kí inú yín máa dùn ninu OLUWA Ọlọrun yín;nítorí ó ti da yín láre, ó ti fun yín ní àkọ́rọ̀ òjò,ó ti rọ ọpọlọpọ òjò fun yín:ati òjò àkọ́rọ̀, ati àrọ̀kẹ́yìn òjò, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀.