1 Ọ̀rọ̀ OLUWA nìyí; tí a kọ sinu ìwé ìran tí Nahumu ará Elikoṣi rí nípa ìlú Ninefe.
2 OLUWA tíí jowú tíí sìí máa gbẹ̀san ni Ọlọrun.OLUWA a máa gbẹ̀san, a sì máa bínú.OLUWA a máa gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀,a sì máa fi ìrúnú rẹ̀ pamọ́ de àwọn ọ̀tá rẹ̀.
3 OLUWA kì í tètè bínú;ó lágbára lọpọlọpọ,kì í sìí dá ẹni tí ó bá jẹ̀bi láre.Ipa ọ̀nà rẹ̀ wà ninu ìjì ati ẹ̀fúùfù líle,awọsanma sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀.
4 Ó bá òkun wí, ó mú kí ó gbẹ,ó sì mú kí gbogbo odò gbẹ pẹlu;koríko ilẹ̀ Baṣani ati ti òkè Kamẹli gbẹ,òdòdó ilẹ̀ Lẹbanoni sì rẹ̀.
5 Àwọn òkè ńláńlá mì tìtì níwájú rẹ̀,àwọn òkè kéékèèké sì yọ́.Ilẹ̀ di asán níwájú rẹ̀,ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ di òfo.
6 Bí ó bá ń bínú ta ló lè dúró?Ta ló lè farada ibinu gbígbóná rẹ̀?Ìrúnú rẹ̀ a máa ru jáde bí ahọ́n iná,a sì máa fọ́ àwọn àpáta níwájú rẹ̀.
7 OLUWA ṣeun,òun ni ibi ààbò ní ọjọ́ ìdààmú;ó sì mọ àwọn tí wọn ń sálọ sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ààbò.
8 Bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀ni yóo ṣe mú ìparun bá àwọn ọ̀tá rẹ̀;yóo sì lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀ bọ́ sí inú òkùnkùn.
9 Èrò ibi wo ni ẹ̀ ń gbà sí OLUWA?Yóo wulẹ̀ pa yín run patapata ni;kò sì sí ẹni tí OLUWA yóo gbẹ̀san lára rẹ̀ lẹ́ẹ̀kantí yóo lè ṣẹ̀ ẹ́ lẹẹkeji.
10 Wọn yóo jóná bí igbó ẹlẹ́gùn-ún tí ó dí,àní bíi koríko gbígbẹ.
11 Ṣebí ọ̀kan ninu yín ni ó ń gbìmọ̀ burúkú sí OLUWA, tí ó sì ń fúnni ní ìmọ̀ràn burúkú?
12 OLUWA wí pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Siria lágbára, tí wọ́n sì pọ̀, a óo pa wọ́n run, wọn yóo sì parẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti jẹ ẹ̀yin ọmọ Juda níyà tẹ́lẹ̀, n kò ní jẹ yín níyà mọ́.
13 N óo bọ́ àjàgà Asiria kúrò lọ́rùn yín, n óo sì já ìdè yín.”
14 OLUWA ti pàṣẹ nípa Asiria, pé: “A kò ní ranti orúkọ rẹ mọ́, ìwọ ilẹ̀ Asiria, n óo run àwọn ère tí ẹ̀yin ará Asiria gbẹ́, ati àwọn tí ẹ dà, tí wọ́n wà ní ilé oriṣa rẹ, n óo gbẹ́ ibojì rẹ, nítorí ẹlẹ́gbin ni ọ́.”
15 Wo ẹsẹ̀ ẹni tí ó ń mú ìyìn rere wá lórí àwọn òkè ńláńlá, ẹni tí ń kéde alaafia! Ẹ máa ṣe àwọn àjọ̀dún yín, ẹ̀yin ará Juda, kí ẹ sì san àwọn ẹ̀jẹ́ yín, nítorí ẹni ibi kò ní gbógun tì yín mọ́, a ti pa á run patapata.