1 Atúniká ti gbógun tì ọ́, ìwọ Ninefe.Yan eniyan ṣọ́ ibi ààbò;máa ṣọ́nà, di àmùrè rẹ,kí o sì múra ogun.
2 (Nítorí OLUWA ti ṣetán láti dá ògo Jakọbu padabí ògo Israẹli,nítorí àwọn tí wọn ń kóni lẹ́rú ti kó wọn,wọ́n sì ti ba àwọn ẹ̀ka wọn jẹ́.)
3 Pupa ni asà àwọn akọni rẹ̀,ẹ̀wù pupa ni àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wọ̀Kẹ̀kẹ́ ogun wọn ń kọ mànàbí ọwọ́ iná;nígbà tí wọ́n tò wọ́n jọ,àwọn ẹṣin wọn ń yan.
4 Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ń dà wọ ìgboro pẹlu ariwo,wọ́n ń sáré sókè sódò ní gbàgede;wọ́n mọ́lẹ̀ yòò bí iná ìtùfù,wọ́n ń kọ mànà bí mànàmáná.
5 Ó pe àwọn ọ̀gágun rẹ̀ jọ,wọ́n sì ń fẹsẹ̀ kọ bí wọ́n ti ń lọ,wọ́n yára lọ sí ibi odi,wọ́n sì fi asà dira ogun.
6 Àwọn ìlẹ̀kùn odò ṣí sílẹ̀,ìdàrúdàpọ̀ wà láàfin.
7 A tú ayaba sí ìhòòhò,a sì mú un lọ sí ìgbèkùn,àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ ń dárò rẹ̀,wọ́n káwọ́ lérí,wọ́n ń rin bí oriri.
8 Ìlú Ninefe dàbí adágún odòtí omi rẹ̀ ti ṣàn lọ.Wọ́n ń kígbe pé, “Ẹ dúró! Ẹ dúró!”Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó yíjú pada.
9 Ẹ kó fadaka,ẹ kó wúrà!Ìlú náà kún fún ìṣúra,ati àwọn nǹkan olówó iyebíye.
10 A ti pa Ninefe run! Ó ti dahoro!Ọkàn àwọn eniyan ti dàrú,orúnkún wọn ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀,ìrora dé bá ọpọlọpọ,gbogbo ojú wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.
11 Níbo ni ìlú tí ó dàbí ihò àwọn kinniun wà?Tí ó rí bí ibùgbé àwọn ọ̀dọ́ kinniun?Ibi tí kinniun ń gbé oúnjẹ rẹ̀ lọ,tí àwọn ọmọ rẹ̀ wà,tí kò sí ẹni tí ó lè dà wọ́n láàmú?
12 Akọ kinniun a máa fa ẹran yafún àwọn ọmọ rẹ̀,a sì máa lọ́ ẹran lọ́rùn pafún àwọn abo rẹ̀;a máa kó ẹran tí ó bá paati èyí tí ó fàya sinu ihò rẹ̀.
13 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wò ó! Mo ti dójú lé ọ. N óo dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ, n óo sì fi idà pa àwọn ọmọ ogun rẹ. Gbogbo ohun tí o ti gbà lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn ni n óo gbà pada lọ́wọ́ rẹ; a kò sì ní gbọ́ ohùn àwọn iranṣẹ rẹ mọ́.”