1 Atúniká ti gbógun tì ọ́, ìwọ Ninefe.Yan eniyan ṣọ́ ibi ààbò;máa ṣọ́nà, di àmùrè rẹ,kí o sì múra ogun.
2 (Nítorí OLUWA ti ṣetán láti dá ògo Jakọbu padabí ògo Israẹli,nítorí àwọn tí wọn ń kóni lẹ́rú ti kó wọn,wọ́n sì ti ba àwọn ẹ̀ka wọn jẹ́.)
3 Pupa ni asà àwọn akọni rẹ̀,ẹ̀wù pupa ni àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wọ̀Kẹ̀kẹ́ ogun wọn ń kọ mànàbí ọwọ́ iná;nígbà tí wọ́n tò wọ́n jọ,àwọn ẹṣin wọn ń yan.
4 Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ń dà wọ ìgboro pẹlu ariwo,wọ́n ń sáré sókè sódò ní gbàgede;wọ́n mọ́lẹ̀ yòò bí iná ìtùfù,wọ́n ń kọ mànà bí mànàmáná.
5 Ó pe àwọn ọ̀gágun rẹ̀ jọ,wọ́n sì ń fẹsẹ̀ kọ bí wọ́n ti ń lọ,wọ́n yára lọ sí ibi odi,wọ́n sì fi asà dira ogun.
6 Àwọn ìlẹ̀kùn odò ṣí sílẹ̀,ìdàrúdàpọ̀ wà láàfin.