4 Nítorí ọpọlọpọ ìwà àgbèrè Ninefe,tí wọ́n fanimọ́ra,ṣugbọn tí wọ́n kún fún òògùn olóró,ni gbogbo ìjìyà yìí ṣe dé bá a;nítorí ó ń fi ìwà àgbèrè rẹ̀ tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ,ó sì ń fi òògùn rẹ̀ mú àwọn eniyan.
5 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní:“Wò ó! Mo ti gbógun tì ọ́, Ninefe,n óo ká aṣọ kúrò lára rẹ, n óo fi bò ọ́ lójú;n óo tú ọ sí ìhòòhò lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn yóo rí ìhòòhò rẹojú yóo sì tì ọ́.
6 N óo mú ẹ̀gbin bá ọ n óo fi àbùkù kàn ọ́;n óo sì sọ ọ́ di ẹlẹ́yà ati ẹni àpéwò.
7 Ẹnu yóo ya gbogbo àwọn tí ó bá wò ọ́, wọn yóo máawí pé: ‘Ninefe ti di ahoro; ta ni yóo dárò rẹ̀?Níbo ni n óo ti rí olùtùnú fún ọ?’ ”
8 Ṣé ìwọ Ninefe sàn ju ìlú Tebesi lọ, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ odò Naili, tí omi yíká, tí ó fi òkun ṣe ààbò, tí ó sì fi omi ṣe odi rẹ̀?
9 Etiopia ati Ijipti ni agbára rẹ̀ tí kò lópin; Puti ati Libia sì ni olùrànlọ́wọ́ rẹ̀.
10 Sibẹsibẹ àwọn ọ̀tá kó o lọ sí ìgbèkùn, wọ́n ṣán àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, wọ́n pa wọ́n ní ìpakúpa ní gbogbo àwọn ìkóríta wọn. Wọ́n ṣẹ́ gègé lórí àwọn ọlọ́lá ibẹ̀, wọ́n sì fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn eniyan pataki wọn.