16 Ó làjà láàrin àwọn mejeeji, ó sọ wọ́n di ara kan lọ́dọ̀ Ọlọrun nípa agbelebu. Ó ti mú odì yíyàn dópin lórí agbelebu.
17 Nígbà tí ó dé, ó waasu ìyìn rere alaafia fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní ọ̀nà jíjìn, ó sì waasu ìyìn rere alaafia fún àwọn tí ó wà nítòsí.
18 Nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni àwa mejeeji ṣe rí ààyè láti dé ọ̀dọ̀ Baba nípa Ẹ̀mí kan náà.
19 Nítorí náà, ẹ kì í tún ṣe àlejò ní ìlú àjèjì mọ́, ṣugbọn ẹ jẹ́ ọmọ-ìbílẹ̀ pẹlu àwọn onigbagbọ, ẹ sì di mọ̀lẹ́bí ninu agbo-ilé Ọlọrun.
20 Lórí àwọn aposteli ati àwọn wolii ni a ti fi ìpìlẹ̀ ìdílé yìí lélẹ̀, Kristi Jesu fúnrarẹ̀ sì ni òkúta igun ilé.
21 Òun ni ó mú kí gbogbo ilé dúró dáradára, tí ó sì mú un dàgbà láti di ilé ìsìn mímọ́ fún Oluwa.
22 Ẹ̀mí ń kọ́ àwa ati ẹ̀yin papọ̀ ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi kí á lè di ibùgbé Ọlọrun.