13 Nítorí èyí, mò ń gbadura pé kí ọkàn yín má ṣe rẹ̀wẹ̀sì nítorí ìpọ́njú tí mò ń rí nítorí yín. Ohun ìṣògo ni èyí jẹ́ fun yín.
14 Nítorí èyí ni mo ṣe ń fi ìkúnlẹ̀ gbadura sí Baba,
15 tí à ń fi orúkọ rẹ̀ pe gbogbo ìdílé lọ́run ati láyé.
16 Mò ń gbadura pé, gẹ́gẹ́ bíi títóbi ògo rẹ̀, kí ó fun yín ní agbára Ẹ̀mí rẹ̀ tí yóo fún ọkàn yín ní okun;
17 kí Kristi fi ọkàn yín ṣe ilé nípa igbagbọ kí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu ìfẹ́, kí ìpìlẹ̀ ìgbé-ayé yín jẹ́ ti ìfẹ́,
18 kí ẹ lè ní agbára, pẹlu gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun, láti mọ bí ìfẹ́ Kristi ti gbòòrò tó, bí ó ti gùn tó, bí ó ti ga tó, ati bí ó ti jìn tó;
19 kí ẹ lè mọ bí ìfẹ́ Kristi ti tayọ ìmọ̀ ẹ̀dá tó, kí ẹ sì lè kún fún gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọrun.