7 Ṣebí àwọn ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí orúkọ rere tí a fi ń pè yín!
8 Ẹ̀ ń ṣe dáradára tí ẹ bá pa òfin ìjọba Ọlọrun mọ́, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé, “Ìwọ fẹ́ràn ọmọnikeji rẹ bí o ti fẹ́ràn ara rẹ.”
9 Ṣugbọn tí ẹ bá ń ṣe ojuṣaaju, ẹ di arúfin, ati ẹni ìbáwí lábẹ́ òfin gẹ́gẹ́ bí arúfin.
10 Nítorí ẹni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, ṣugbọn tí ó rú ẹyọ kan ṣoṣo, ó jẹ̀bi gbogbo òfin.
11 Nítorí ẹnìkan náà tí ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè,” òun náà ni ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ paniyan.” Bí o kò bá ṣe àgbèrè ṣugbọn o paniyan, o ti di arúfin.
12 Ẹ máa sọ̀rọ̀, kí ẹ sì máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó wà lábẹ́ ìdájọ́ òfin tí ó ń sọ eniyan di òmìnira.
13 Nítorí kò ní sí àánú ninu ìdájọ́ fún àwọn tí kò ní ojú àánú, bẹ́ẹ̀ sì ni àánú ló borí ìdájọ́.