7 Gbogbo ẹ̀dá pátá: ati ẹranko ni, ati ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà, ati àwọn ẹran omi, gbogbo wọn ni eniyan lè so lójú rọ̀.
8 Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó kápá ahọ́n. Nǹkan burúkú tí ó kanpá ni, ó kún fún oró tí ó lè paniyan kíákíá.
9 Ahọ́n ni a fi ń yin Oluwa ati Baba. Òun kan náà ni a fi ń ṣépè fún eniyan tí a dá ní àwòrán Ọlọrun.
10 Láti inú ẹnu kan náà ni ìyìn ati èpè ti ń jáde. Ẹ̀yin ará mi, kò yẹ kí èyí rí bẹ́ẹ̀.
11 Ǹjẹ́ omi dídùn ati omi kíkorò lè ti inú orísun omi kan náà jáde?
12 Ẹ̀yin ará mi, ṣé igi ọ̀pọ̀tọ́ lè so èso olifi, tabi kí àjàrà kó so ọ̀pọ̀tọ́? Ìsun omi kíkorò kò lè mú omi dídùn jáde.
13 Ẹnikẹ́ni wà láàrin yín tí ó gbọ́n, tí ó tún mòye? Kí ó fihàn nípa ìgbé-ayé rere ati ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí ó fi ọgbọ́n hàn.