7 Olùfẹ́, kì í ṣe òfin titun ni mò ń kọ si yín. Òfin àtijọ́ tí ẹ ti níláti ìbẹ̀rẹ̀ ni. Òfin àtijọ́ náà ni ọ̀rọ̀ tí ẹ ti gbọ́.
8 Ṣugbọn ní ìdàkejì, òfin titun ni mò ń kọ si yín, èyí tí a rí òtítọ́ rẹ̀ ninu Jesu Kristi ati ninu yín, nítorí pé òkùnkùn ń kọjá lọ, ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ sì ti ń tàn.
9 Ẹni tí ó bá wí pé òun wà ninu ìmọ́lẹ̀, tí ó kórìíra arakunrin rẹ̀, wà ninu òkùnkùn sibẹ.
10 Ẹni tí ó bá fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, ohun ìkọsẹ̀ kò sí ninu olúwarẹ̀.
11 Ṣugbọn ẹni tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀ wà ninu òkùnkùn; kò mọ ibi tí ó ń lọ, nítorí òkùnkùn ti fọ́ ọ lójú.
12 Ẹ̀yin ọmọde, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé a ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín nítorí orúkọ Jesu.
13 Ẹ̀yin baba, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ ẹni tí ó wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé. Ẹ̀yin ọdọmọkunrin, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti ṣẹgun Èṣù. Ẹ̀yin ọmọde, mo kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ Baba.