Johanu Kinni 5 BM

Igbagbọ ni Ìṣẹ́gun lórí Ayé

1 Gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Jesu ni Mesaya, a bí i láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ràn baba yóo fẹ́ràn Ọmọ rẹ̀.

2 Ọ̀nà tí a fi lè mọ̀ pé a fẹ́ràn àwọn ọmọ Ọlọrun ni pé kí á fẹ́ràn Ọlọrun kí á sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.

3 Fífẹ́ràn Ọlọrun ni pé kí á pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́: àwọn àṣẹ rẹ̀ kò sì wọni lọ́rùn,

4 nítorí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọrun ti ṣẹgun ayé. Igbagbọ wa ni ìṣẹ́gun lórí ayé.

5 Ta ni ó ti ṣẹgun ayé? Àfi ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu.

Ẹ̀rí nípa Ọmọ

6 Òun yìí ni ó wà nípa omi ati ẹ̀jẹ̀, àní Jesu Kristi. Kì í ṣe nípa omi nìkan, ṣugbọn nípa omi ati ẹ̀jẹ̀. Ẹ̀mí ni ó ń jẹ́rìí, nítorí òtítọ́ ni Ẹ̀mí.

7 Àwọn ẹlẹ́rìí mẹta ni ó wà:

8 Ẹ̀mí, omi ati ẹ̀jẹ̀. Nǹkankan náà ni àwọn mẹtẹẹta ń tọ́ka sí.

9 À ń gba ẹ̀rí eniyan, ṣugbọn ẹ̀rí Ọlọrun tóbi ju ti eniyan lọ; nítorí ẹ̀rí Ọlọrun ni, tí ó jẹ́ nípa Ọmọ rẹ̀.

10 Ẹni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọrun gbọ́ ní ẹ̀rí yìí ninu ara rẹ̀. Ẹni tí kò bá gba Ọlọrun gbọ́ mú Ọlọrun lékèé, nítorí kò gba ẹ̀rí tí Ọlọrun ti jẹ́ nípa Ọmọ rẹ̀ gbọ́.

11 Ẹ̀rí náà ni pé Ọlọrun ti fún wa ní ìyè ainipẹkun, ìyè yìí sì wà ninu Ọmọ rẹ̀.

12 Ẹni tí ó bá ní Ọmọ ní ìyè; ẹni tí kò bá ní Ọmọ Ọlọrun kò ní ìyè.

Ìyè Ainipẹkun

13 Mo kọ èyí si yín, ẹ̀yin tí ẹ gba orúkọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́, kí ẹ lè mọ̀ pé ẹ ní ìyè ainipẹkun.

14 Ìgboyà tí a ní níwájú Ọlọrun nìyí, pé bí a bá bèèrè ohunkohun ní ọ̀nà tí ó fẹ́, yóo gbọ́ tiwa.

15 Bí a bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tiwa nípa ohunkohun tí a bá bèèrè, a mọ̀ pé à ń rí gbogbo ohun tí a bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ gbà.

16 Bí ẹnikẹ́ni bá rí arakunrin rẹ̀ tí ó ń dẹ́ṣẹ̀ kan, tí kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ó jẹ mọ́ ti ikú, kí ó gbadura fún un, Ọlọrun yóo fún un ní ìyè. Mò ń sọ nípa àwọn tí wọn ń dẹ́ṣẹ̀ tí kò jẹ mọ́ ti ikú. Ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn wà tí ó la ti ikú lọ. N kò wí pé kí eniyan gbadura fún irú rẹ̀.

17 Gbogbo aiṣododo ni ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn wà tí kò jẹ mọ́ ti ikú.

18 A mọ̀ pé kò sí ọmọ Ọlọrun kan tíí máa gbé inú ẹ̀ṣẹ̀, nítorí pé Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun ń pa á mọ́, Èṣù kò sì ní fọwọ́ kàn án.

19 A mọ̀ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti wá, ati pé gbogbo ayé patapata wà lábẹ́ Èṣù.

20 A tún mọ̀ pé Ọmọ Ọlọrun ti dé, ó ti fún wa ní làákàyè kí á lè mọ ẹni Òtítọ́. À ń gbé inú Ọlọrun, àní inú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Òun ni Ọlọrun tòótọ́ ati ìyè ainipẹkun.

21 Ẹ̀yin ọmọde, ẹ má bá wọn bọ oriṣa.

orí

1 2 3 4 5