Johanu Kinni 4 BM

Ẹ̀mí Ọlọrun ati Ẹ̀mí Alátakò Kristi

1 Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹni tí ó bá wí pé òun ní Ẹ̀mí Ọlọrun gbọ́. Ẹ kọ́kọ́ wádìí wọn láti mọ ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, nítorí ọpọlọpọ àwọn èké wolii ti wọ inú ayé.

2 Ọ̀nà tí a óo fi mọ Ẹ̀mí Ọlọrun nìyí: gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá sáyé gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran-ara jẹ́ ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

3 Gbogbo ẹni tí kò bá jẹ́wọ́ bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ti Ọlọrun. Alátakò Kristi tí ẹ ti gbọ́ pé ó ń bọ̀ ni irú ẹni bẹ́ẹ̀. Ó ti dé inú ayé nisinsinyii.

4 Ẹ̀yin ọmọde, ti Ọlọrun nìyí, ẹ ti ṣẹgun ẹ̀mí alátakò Kristi nítorí pé ẹni tí ó wà ninu yín tóbi ju ẹni tí ó wà ninu ayé lọ.

5 Láti inú ayé ni àwọn yìí ti wá; nítorí náà, wọ́n ń sọ nǹkan ti ayé, àwọn aráyé sì ń gbọ́ tiwọn.

6 Ti Ọlọrun ni àwa; Ẹni tí ó bá mọ Ọlọrun ń gbọ́ tiwa; ẹni tí kì í bá ṣe ti Ọlọrun kò ní gbọ́ tiwa. Ọ̀nà tí a fi mọ Ẹ̀mí òtítọ́ ati ẹ̀mí ìtànjẹ yàtọ̀ nìyí.

Ìfẹ́ ni Ọlọrun

7 Olùfẹ́, ẹ jẹ́ kí á fẹ́ràn ẹnìkejì wa, nítorí ìfẹ́ ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá. Ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti bí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìfẹ́, ó sì mọ Ọlọrun.

8 Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ kò mọ Ọlọrun nítorí ìfẹ́ ni Ọlọrun.

9 Ọ̀nà tí Ọlọrun fi fi ìfẹ́ tí ó ní sí wa hàn ni pé ó ti rán ààyò ọmọ rẹ̀ wá sáyé kí á lè ní ìgbàlà nípasẹ̀ rẹ̀.

10 Ọ̀nà tí a fi mọ ìfẹ́ nìyí: kì í ṣe pé àwa ni a fẹ́ràn Ọlọrun ṣugbọn òun ni ó fẹ́ràn wa, tí ó rán ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti jẹ́ ọ̀nà ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa.

11 Olùfẹ́, bí Ọlọrun bá fẹ́ràn wa tó báyìí, ó yẹ kí àwa náà fẹ́ràn ọmọnikeji wa.

12 Ẹnikẹ́ni kò rí Ọlọrun rí, bí a bá fẹ́ràn ọmọnikeji wa, Ọlọrun ń gbé inú wa, ìfẹ́ rẹ̀ sì ti di pípé ninu wa.

13 A mọ̀ pé à ń gbé inú Ọlọrun ati pé òun náà ń gbé inú wa nítorí pé ó fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀.

14 Àwa ti rí i, a sì ń jẹ́rìí pé Baba ti rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ olùgbàlà aráyé.

15 Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu, Ọlọrun ń gbé inú rẹ̀, òun náà sì ń gbé inú Ọlọrun.

16 A mọ ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí wa, a sì ní igbagbọ ninu ìfẹ́ yìí.Ìfẹ́ ni Ọlọrun. Ẹni tí ó bá ń gbé inú ìfẹ́ ń gbé inú Ọlọrun, Ọlọrun náà sì ń gbé inú rẹ̀.

17 Nípa bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ ṣe di pípé ninu wa, kí á lè ní ìgboyà ní ọjọ́ ìdájọ́ pé bí ó ti rí ni àwa náà rí ninu ayé yìí.

18 Kò sí ẹ̀rù ninu ìfẹ́; ìfẹ́ pípé a máa lé ẹ̀rù jáde, nítorí ìjayà ni ó ń mú ẹ̀rù wá. Ẹni tí ó bá ń bẹ̀rù kò ì tíì di pípé ninu ìfẹ́.

19 A fẹ́ràn rẹ̀ nítorí pé Ọlọrun ni ó kọ́ fẹ́ràn wa.

20 Bí ẹnikẹ́ni bá wí pé, òun fẹ́ràn Ọlọrun, tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀, èké ni. Nítorí ẹni tí kò bá fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ tí ó ń fojú rí, kò lè fẹ́ràn Ọlọrun tí kò rí.

21 Àṣẹ tí a rí gbà láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi ni pé ẹni tí ó bá fẹ́ràn Ọlọrun, kí ó fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ pẹlu.

orí

1 2 3 4 5