25 Ìyá Jesu ati arabinrin ìyá rẹ̀ ati Maria aya Kilopasi ati Maria Magidaleni dúró lẹ́bàá agbelebu Jesu.
26 Nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ ati ọmọ-ẹ̀yìn tí ó fẹ́ràn tí wọ́n dúró, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obinrin, wo ọmọ rẹ.”
27 Ó bá sọ fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ.” Láti ìgbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà ti mú ìyá Jesu lọ sílé ara rẹ̀.
28 Lẹ́yìn èyí, nígbà tí Jesu mọ̀ pé ohun gbogbo ti parí, kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ, ó ní, “Òùngbẹ ń gbẹ mí.”
29 Àwo ọtí kan wà níbẹ̀. Wọ́n bá fi kinní kan bíi kànìnkànìn bọ inú ọtí náà, wọ́n fi sórí ọ̀pá gígùn kan, wọ́n nà án sí i lẹ́nu.
30 Lẹ́yìn tí Jesu ti gba ọtí náà tán, ó wí pé, “Ó ti parí!”Lẹ́yìn náà ó tẹrí ba, ó bá dákẹ́.
31 Nítorí ọjọ́ náà jẹ́ ìpalẹ̀mọ́ Àjọ̀dún Ìrékọjá, kí òkú má baà wà lórí agbelebu ní Ọjọ́ Ìsinmi, àwọn Juu bẹ Pilatu pé kí ó jẹ́ kí wọ́n dá àwọn tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu ní ojúgun, kí wọ́n gbé wọn kúrò lórí agbelebu nítorí pé Ọjọ́ Ìsinmi pataki ni Ọjọ́ Ìsinmi náà.