4 Mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun mi nígbà gbogbo nítorí yín, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fun yín ninu Kristi Jesu.
5 Nítorí pé ẹ ní ọpọlọpọ ẹ̀bùn ninu Kristi: ẹ ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ, ẹ sì tún ní ẹ̀bùn ìmọ̀.
6 Ẹ̀rí Kristi ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ láàrin yín,
7 tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé kò sí ẹ̀bùn Ẹ̀mí kan tí ó kù tí ẹ kò ní. Ẹ wá ń fi ìtara retí ìfarahàn Oluwa wa Jesu Kristi,
8 ẹni tí yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ títí dé òpin, tí ẹ óo fi wà láì lẹ́gàn ní ọjọ́ ìfarahàn Oluwa wa, Jesu Kristi.
9 Ẹni tí ó tó gbẹ́kẹ̀lé ni Ọlọrun tí ó pè yín sinu ìṣọ̀kan pẹlu ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi, Oluwa wa.
10 Ẹ̀yin ará, mo fi orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi bẹ̀ yín, gbogbo yín, ẹ fohùn ṣọ̀kan, kí ó má sí ìyapa láàrin yín. Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín ṣe ọ̀kan, kí èrò yín sì papọ̀.