Kọrinti Kinni 10 BM

Ìkìlọ̀ Nípa Ìbọ̀rìṣà

1 Ẹ̀yin ará, ẹ má gbàgbé pé gbogbo àwọn baba wa ni wọ́n wà lábẹ́ ìkùukùu. Gbogbo wọn ni wọ́n la òkun kọjá.

2 Gbogbo wọn ni wọ́n ṣe ìrìbọmi ninu ìkùukùu ati ninu òkun, kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn Mose.

3 Gbogbo wọn ni wọ́n jẹ oúnjẹ ẹ̀mí kan náà.

4 Gbogbo wọn ni wọ́n mu omi ẹ̀mí kan náà, nítorí wọ́n mu omi tí ó jáde láti inú òkúta ẹ̀mí tí ó ń tẹ̀lé wọn. Òkúta náà ni Kristi.

5 Ṣugbọn sibẹ inú Ọlọrun kò dùn sí ọpọlọpọ ninu wọn, nítorí ọpọlọpọ wọn ni wọ́n kú dànù káàkiri ninu aṣálẹ̀.

6 Àwọn nǹkan wọnyi jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa, pé kí á má ṣe kó nǹkan burúkú lé ọkàn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ti kó o lé ọkàn.

7 Kí ẹ má sì di abọ̀rìṣà bí àwọn mìíràn ninu wọn. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Àwọn eniyan náà jókòó láti jẹ ati láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣe àríyá.”

8 Bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè bí àwọn mìíràn ninu wọn ti ṣe àgbèrè, tí ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹẹdogun (23,000) eniyan fi kú ní ọjọ́ kan.

9 Bẹ́ẹ̀ ni kí á má ṣe dán Oluwa wò, bí àwọn mìíràn ninu wọn ti dán an wò, tí ejò fi ṣán wọn pa.

10 Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe kùn bí àwọn mìíràn ninu wọn ṣe kùn, tí Apani sì pa wọ́n.

11 Gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn yìí jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa. A kọ wọ́n sílẹ̀ kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa, àwa tí a wà ní ìgbà ìkẹyìn.

12 Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kí ó ṣọ́ra kí ó má baà ṣubú.

13 Kò sí ìdánwò kan tí ó dé ba yín bíkòṣe irú èyí tí ó wọ́pọ̀ láàrin eniyan. Ṣugbọn Ọlọrun tó gbẹ́kẹ̀lé, kò ní jẹ́ kí ẹ rí ìdánwò tí ó ju èyí tí ẹ lè fara dà lọ. Ṣugbọn ní àkókò ìdánwò, yóo pèsè ọ̀nà àbáyọ, yóo sì mú kí ẹ lè fara dà á.

14 Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.

15 Mò ń ba yín sọ̀rọ̀ bí ọlọ́gbọ́n. Ẹ̀yin fúnra yín náà, ẹ gba ohun tí mò ń sọ rò.

16 Ife ibukun tí à ń dúpẹ́ fún, ṣebí àjọpín ninu ẹ̀jẹ̀ Kristi ni. Burẹdi tí a bù, ṣebí àjọpín ninu ara Kristi ni.

17 Nítorí burẹdi kan ni ó wà, ninu ara kan yìí ni gbogbo wa sì wà, nítorí ninu burẹdi kan ni gbogbo wa ti ń jẹ.

18 Ẹ ṣe akiyesi ìṣe àwọn ọmọ Israẹli. Ṣebí àwọn tí ń jẹ ẹbọ ń jẹ ninu anfaani lílo pẹpẹ ìrúbọ fún ìsìn Ọlọrun?

19 Nítorí náà, ṣé ohun tí mò ń sọ ni pé ohun tí a fi rúbọ fún oriṣa jẹ́ nǹkan? Tabi pé oriṣa jẹ́ nǹkan?

20 Rárá o! Ohun tí mò ń sọ ni pé àwọn nǹkan tí àwọn abọ̀rìṣà fi ń rúbọ, ẹ̀mí burúkú ni wọ́n fi ń rúbọ sí, kì í ṣe Ọlọrun. N kò fẹ́ kí ẹ ní ìdàpọ̀ pẹlu àwọn ẹ̀mí burúkú.

21 Ẹ kò lè mu ninu ife Oluwa tán kí ẹ tún lọ mu ninu ife ti ẹ̀mí burúkú. Ẹ kò lè jẹ ninu oúnjẹ orí tabili Oluwa, kí ẹ tún lọ jẹ ninu oúnjẹ orí tabili ẹ̀mí burúkú.

22 Àbí a fẹ́ mú Oluwa jowú ni bí? Àbí a lágbára jù ú lọ ni?

Ẹ Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọrun

23 Lóòótọ́, “Ohun tí a bá fẹ́ ni a lè ṣe,” bí àwọn kan ti ń wí. Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan ni ó ń ṣe eniyan ní anfaani. “Ohun tí a bá fẹ́ ni a lè ṣe.” Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan tí a lè ṣe ni ó ń mú ìdàgbà wá.

24 Kí ẹnikẹ́ni má ṣe máa wá ire ti ara rẹ̀ bíkòṣe ire ẹnìkejì rẹ̀.

25 Kí ẹ jẹ ohunkohun tí ẹ bá rà ní ọjà láì wádìí ohunkohun kí ẹ̀rí-ọkàn yín lè mọ́;

26 “Nítorí Oluwa ni ó ni ayé ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀.”

27 Bí ẹnìkan ninu àwọn alaigbagbọ bá pè yín wá jẹun, tí ẹ bá gbà láti lọ, ẹ jẹ ohunkohun tí ó bá gbé kalẹ̀ níwájú yín láì wádìí ohunkohun, kí ẹ̀rí-ọkàn yín lè mọ́.

28 Ṣugbọn bí ẹnìkan bá sọ fun yín pé, “A ti fi oúnjẹ yìí ṣe ìrúbọ,” ẹ má jẹ ẹ́, nítorí ẹni tí ó sọ bẹ́ẹ̀ ati nítorí ẹ̀rí-ọkàn.

29 Kì í ṣe ẹ̀rí-ọkàn tiyín ni mò ń sọ bíkòṣe ẹ̀rí-ọkàn ti ẹni tí ó pe akiyesi yín sí oúnjẹ náà.Kí ló dé tí yóo fi jẹ́ pé ẹ̀rí-ọkàn ẹlòmíràn ni yóo máa sọ bí n óo ti ṣe lo òmìníra mi?

30 Bí mo bá jẹ oúnjẹ pẹlu ọpẹ́ sí Ọlọrun, ẹ̀tọ́ wo ni ẹnìkan níláti bá mi wí fún ohun tí mo ti dúpẹ́ fún?

31 Nítorí náà, ìbáà jẹ́ pé ẹ̀ ń jẹ ni, tabi pé ẹ̀ ń mu ni, ohunkohun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ máa ṣe é fún ògo Ọlọrun.

32 Ẹ má ṣe jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún àwọn Juu tabi fún àwọn tí kì í ṣe Juu tabi fún ìjọ Ọlọrun.

33 Ní tèmi, mò ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí ó wu gbogbo eniyan ní gbogbo ọ̀nà. Kì í ṣe ohun tí ó jẹ́ anfaani tèmi ni mò ń wá, bíkòṣe ohun tí ó jẹ́ anfaani ọpọlọpọ eniyan, kí á lè gbà wọ́n là.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16