Kọrinti Kinni 16 BM

Ìtọrẹ Onigbagbọ

1 Nípa ti ìtọrẹ tí ẹ̀ ń ṣe fún àwọn eniyan Ọlọrun, bí mo ti ṣe ètò pẹlu àwọn ìjọ Galatia, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe.

2 Ní ọjọọjọ́ ìsinmi, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín máa mú ọrẹ ninu ohun ìní rẹ̀, kí ó máa fi í sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun bá ti bukun un. Kí ó má ṣe jẹ́ pé nígbà tí mo bá dé ni ẹ óo ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gba ọrẹ jọ.

3 Nígbà tí mo bá dé, n óo kọ ìwé lé àwọn tí ẹ bá yàn lọ́wọ́, n óo rán wọn láti mú ọrẹ yín lọ sí Jerusalẹmu.

4 Bí ó bá yẹ kí èmi náà lọ, wọn yóo bá mi lọ.

Ètò Nípa Ìrìn Àjò

5 Masedonia ni n óo kọ́ gbà kọjá, n óo wá wá sọ́dọ̀ yín.

6 Bóyá n óo dúró lọ́dọ̀ yín, mo tilẹ̀ lè wà lọ́dọ̀ yín ní àkókò òtútù, kí ẹ lè sìn mí lọ sí ibi tí mo bá tún ń lọ.

7 Nítorí pé, nígbà tí mo bá ń kọjá lọ, n kò fẹ́ kí ó jẹ́ pé mo kàn fi ojú bà yín lásán ni. Nítorí mo ní ìrètí pé n óo lè dúró lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀, bí Oluwa bá gbà bẹ́ẹ̀.

8 Mo fẹ́ dúró ní Efesu níhìn-ín títí di àjọ̀dún Pẹntikọsti.

9 Nítorí pé mo ní anfaani pupọ láti ṣiṣẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alátakò pọ̀.

10 Bí Timoti bá dé, kí ẹ rí i pé ẹ fi í lára balẹ̀ láàrin yín, nítorí iṣẹ́ Oluwa tí mò ń ṣe ni òun náà ń ṣe.

11 Kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi àbùkù kàn án. Ẹ ṣe ètò ìrìn àjò fún un ní alaafia, kí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, nítorí èmi ati àwọn arakunrin ń retí rẹ̀.

12 Nípa ti arakunrin wa Apolo, mo gbà á níyànjú gidigidi pé kí ó wá sọ́dọ̀ yín pẹlu àwọn arakunrin yòókù. Ṣugbọn ó pinnu pé òun kò fẹ́ wá ní àkókò yìí. Ó ń bọ̀ nígbà tí ó bá yá.

Gbolohun Ìparí

13 Ẹ máa ṣọ́nà. Ẹ dúró gbọningbọnin ninu igbagbọ. Ẹ ṣe bí ọkunrin. Ẹ jẹ́ alágbára.

14 Ẹ máa ṣe gbogbo nǹkan tìfẹ́tìfẹ́.

15 Ará, mo ní ẹ̀bẹ̀ kan láti fi siwaju yín. Ẹ mọ̀ pé ìdílé Stefana ni àwọn kinni tí ó kọ́kọ́ gbàgbọ́ ní ilẹ̀ Akaya; ati pé wọ́n ti yan ara wọn láti máa ṣe iṣẹ́ iranṣẹ fún àwọn eniyan Ọlọrun.

16 Mo fẹ́ kí ẹ máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ irú wọn ati gbogbo àwọn tí wọn bá ń bá wọn ṣiṣẹ́ pọ̀, tí wọn ń ṣe làálàá níbi iṣẹ́ kan náà.

17 Inú mi dùn nígbà tí Stefana ati Fotunatu ati Akaiku dé, nítorí dídé tí wọ́n dé dí àlàfo tí ó ṣí sílẹ̀ nítorí àìsí yín lọ́dọ̀ wa.

18 Wọ́n mú kí ọkàn mi balẹ̀. Ati ti ẹ̀yin náà. Ẹ máa yẹ́ irú àwọn bẹ́ẹ̀ sí.

19 Gbogbo ìjọ tí ó wà ní Esia kí yín. Akuila ati Pirisila ati ìjọ tí ó wà ní ilé wọn ki yín pupọ ninu Oluwa.

20 Gbogbo àwọn onigbagbọ ki yín. Ẹ fi ìfẹnukonu alaafia kí ara yín.

21 Ọwọ́ ara mi ni èmi Paulu fi kọ gbolohun ìkíni yìí.

22 Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ràn Oluwa wa, ẹni ègún ni! Marana ta–Oluwa wa, máa bọ̀!

23 Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu yín.

24 Mo fi ìfẹ́ kí gbogbo yín ninu Kristi Jesu.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16