Kọrinti Keji 1 BM

Ìkíni

1 Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọlọrun, ati Timoti, arakunrin wa, ni à ń kọ ìwé yìí sí Ìjọ Ọlọrun tí ó wà ní Kọrinti ati sí gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun tí ó wà ní Akaya.

2 Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu yín.

Ọpẹ́ lẹ́yìn ìjìyà

3 A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Baba aláàánú ati Ọlọrun orísun ìtùnú,

4 ẹni tí ó ń fún wa ní ìwúrí ninu gbogbo ìpọ́njú tí à ń rí, kí àwa náà lè fi ìwúrí fún àwọn tí ó wà ninu oríṣìíríṣìí ìpọ́njú nípa ìwúrí tí àwa fúnra wa ti níláti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.

5 Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti ní ìpín ninu ọpọlọpọ ìyà Kristi, bẹ́ẹ̀ náà ni a ní ọpọlọpọ ìwúrí nípasẹ̀ Kristi.

6 Ṣugbọn bí a bá wà ninu ìpọ́njú, fún ìwúrí ati ìgbàlà yín ni. Bí a bá ní ìwúrí, ẹ̀yin náà yóo ní ìwúrí; ìwúrí yìí yóo sì kọ yín ní sùúrù nígbà tí ẹ bá ń jẹ irú ìyà tí àwa náà ń jẹ.

7 Ìrètí wa lórí yín sì ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, nítorí tí a mọ̀ pé bí a ti jọ ń jẹ irú ìyà kan náà, bẹ́ẹ̀ náà ni a jọ ní irú ìwúrí kan náà.

8 Ẹ̀yin ará, a kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀ nípa ìpọ́njú tí ó tayọ agbára wa tí a ní ní Esia, Ìdààmú náà wọ̀ wá lọ́rùn tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀mí wa fi fẹ́rẹ̀ bọ́.

9 A ṣe bí wọ́n tí dá wa lẹ́bi ikú ni. Kí á má baà gbẹ́kẹ̀lé ara wa, bíkòṣe Ọlọrun, ni ọ̀rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Nítorí Ọlọrun níí jí òkú dìde.

10 Ọlọrun ni ó yọ wá ninu ewu ńlá náà, òun ni yóo sì máa yọ wá. Òun ni a ní ìrètí ninu rẹ̀; yóo sì tún máa yọ wá,

11 bí ẹ bá ń fi adura yín ràn wá lọ́wọ́. Nígbà náà ni ọpọlọpọ eniyan yóo ṣọpẹ́ nítorí ọpọlọpọ oore tí Ọlọrun ṣe fún wa.

Ìdí Tí Paulu Ṣe Yí Ètò Ìrìn Àjò Rẹ̀ Pada

12 Nǹkankan wà tí a lè fi ṣe ìgbéraga, ẹ̀rí-ọkàn wa sì jẹ́rìí sí i pé pẹlu ọkàn kan ati inú kan níwájú Ọlọrun ni a fi ń bá gbogbo eniyan lò, pàápàá jùlọ ẹ̀yin gan-an. Kì í ṣe ọgbọ́n eniyan bíkòṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.

13 Kò sí ohunkohun tí a kọ si yín tí ẹ kò lè kà kí ó ye yín. Mo sì ní ìrètí pé yóo ye yín jálẹ̀.

14 Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé ẹ kò ì tíì mọ̀ wá dáradára, ẹ óo rí i pé a óo jẹ́ ohun ìṣògo fun yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà yóo ti jẹ́ fún wa ní ọjọ́ tí Oluwa wa, Jesu, bá dé.

15 Nítorí ó dá mi lójú bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe fẹ́ kọ́kọ́ wá sọ́dọ̀ yín, kí ayọ̀ yín lè di ìlọ́po meji.

16 Ǹ bá gba ọ̀dọ̀ yín lọ sí Masedonia, ǹ bá sì tún gba ọ̀dọ̀ yín lábọ̀. Ǹ bá wá ṣe ètò láti wá ìrànlọ́wọ́ fún ìrìn àjò mi sí Judia.

17 Ohun tí mo ní lọ́kàn nìyí. Ǹjẹ́ kò ní ìdí tí mo fi yí ètò yìí pada? Àbí ẹ rò pé nígbà tí mò ń ṣe ètò, mò ń ṣe é bí ẹni tí kò ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ni, tí ó fi jẹ́ pé ẹnu kan náà tí mo fi pe “bẹ́ẹ̀ ni” ni n óo tún fi pe “bẹ́ẹ̀ kọ́?”

18 Gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, ọ̀rọ̀ wa pẹlu yín ti kúrò ní “bẹ́ẹ̀ ni” ati “bẹ́ẹ̀ kọ́.”

19 Nítorí Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun, tí èmi, Silifanu ati Timoti, ń waasu rẹ̀ fun yín, kì í ṣe “bẹ́ẹ̀ ni” ati “bẹ́ẹ̀ kọ́”. Ṣugbọn “bẹ́ẹ̀ ni” ni tirẹ̀.

20 Nítorí gbogbo ìlérí Ọlọrun di “bẹ́ẹ̀ ni” ninu rẹ̀. Ìdí tí a fi ń ṣe “Amin” ní orúkọ rẹ̀ nìyí, nígbà tí a bá ń fi ògo fún Ọlọrun.

21 Ọlọrun ni ó fún àwa ati ẹ̀yin ní ìdánilójú pé a wà ninu Kristi, òun ni ó ti fi òróró yàn wá.

22 Ó ti fi èdìdì rẹ̀ sí wa lára, ó tún fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe onídùúró sí ọkàn wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ohun tí yóo tún fún wa.

23 Mo fi Ọlọrun jẹ́rìí ohun tí n óo sọ yìí. Mo sì fi ẹ̀mí mi búra! Ìdí tí n kò fi wá sí Kọrinti mọ́ ni pé n kò fẹ́ yọ yín lẹ́nu.

24 Kì í ṣe pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ fi agbára ti igbagbọ bọ̀ yín lọ́rùn ni, nítorí ẹ ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu igbagbọ. Ṣugbọn a jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹlu yín ni, kí ẹ lè ní ayọ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13