Kọrinti Keji 8 BM

Àwọn Onigbagbọ Ará Masedonia Lawọ́

1 Ẹ̀yin ará, a fẹ́ kí ẹ mọ ohun tí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ti ṣe láàrin àwọn ìjọ Masedonia.

2 Wọ́n ní ọpọlọpọ ìdánwò nípa ìpọ́njú. Sibẹ wọ́n ní ayọ̀ pupọ. Wọ́n ṣe aláìní pupọ, sibẹ wọ́n lawọ́ gan-an.

3 Nítorí mo jẹ́rìí pé wọ́n sa ipá wọn, wọ́n tilẹ̀ ṣe tayọ agbára wọn, tìfẹ́tìfẹ́ ni wọ́n sì fi ṣe é.

4 Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ìwúrí ni wọ́n fi bẹ̀ wá pé kí á jẹ́ kí àwọn náà lọ́wọ́ ninu iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ yìí fún àwọn onigbagbọ.

5 Wọ́n tilẹ̀ ṣe ju bí a ti lérò lọ, nítorí pé ara wọn pàápàá ni wọ́n kọ́ gbé bùn wá, tí wọ́n sì yọ̀ǹda fún Ọlọrun nípa ìfẹ́ rẹ̀.

6 Ìdí nìyí tí a fi gba Titu níyànjú pé, nígbà tí ó jẹ́ pé òun ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ yìí láàrin yín, kí ó kúkú ṣe é parí.

7 Gbogbo nǹkan wọnyi ni ẹ ní, tí ẹ sì ní lọpọlọpọ: igbagbọ, ọ̀rọ̀ sísọ, ìmọ̀, ati ìtara ní ọ̀nà gbogbo, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ tí ẹ ní sí wa. A fẹ́ kí ìtara yín túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìfẹ́ pẹlu.

8 N kò pa èyí láṣẹ. Mo fi àpẹẹrẹ ìtara àwọn ẹlòmíràn siwaju yín láti fi dán yín wò ni, bóyá ẹ ní ìfẹ́ tòótọ́ tabi ẹ kò ní.

9 Nítorí ẹ mọ oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi, pé nítorí tiwa, òun tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ di aláìní, kí ẹ lè di ọlọ́rọ̀ nípa àìní tirẹ̀.

10 Èrò mi lórí ọ̀rọ̀ yìí ni pé ohun tí ó dára jùlọ fun yín ni. Nígbà tí kì í tíí ṣe pé ẹ ti ń ṣe é nìkan ni, ṣugbọn tìfẹ́tìfẹ́ ni ẹ ti fi ń ṣe é láti ọdún tí ó kọjá,

11 ó tó àkókò wàyí, ẹ ṣe é parí. Irú ìtara tí ẹ fẹ́ fi ṣe é ni kí ẹ fi parí rẹ̀. Kí ẹ ṣe é gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ní tó.

12 Bí ìfẹ́ láti mú ọrẹ wá bá wà, Ọlọrun gba ohun tí eniyan bá mú wá. Ọlọrun kò bèèrè ohun tí eniyan kò ní.

13-14 Kì í ṣe pé, kí àwọn ẹlòmíràn má ṣe nǹkankan, kí ó jẹ́ pé ẹ̀yin nìkan ni ọrùn yóo wọ̀. Ṣugbọn ọ̀ràn kí ẹ jọ pín in ṣe ní dọ́gba-dọ́gba ni. Ní àkókò yìí, ọ̀pọ̀ tí ẹ ní yóo mú kí ẹ lè pèsè fún àìní àwọn tí ẹ̀ ń rànlọ́wọ́. Ní ọjọ́ iwájú, ọ̀pọ̀ tí àwọn náà bá ní yóo mú kí wọ́n lè pèsè fún àìní yín. Ọ̀rọ̀ ojuṣaaju kò ní sí níbẹ̀.

15 Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, “Ẹni tí ó kó ọ̀pọ̀ kò ní jù, ẹni tí ó kó díẹ̀ kò ṣe aláìní tó.”

Titu ati Àwọn Ẹlẹgbẹ́ Rẹ̀

16 Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó fi irú ìtara kan náà tí mo ní sí ọkàn Titu.

17 Nítorí nígbà tí a sọ pé kí ó wá sọ́dọ̀ yín, pẹlu ayọ̀ ni ó fi gbà láti wá. Òun fúnrarẹ̀ tilẹ̀ ní àníyàn láti wá sọ́dọ̀ yín tẹ́lẹ̀.

18 A rán arakunrin tí ó lókìkí ninu gbogbo àwọn ìjọ nítorí iṣẹ́ rẹ̀ nípa ìyìn rere pé kí ó bá a wá.

19 Kì í ṣe pé ó lókìkí nìkan ni, ṣugbọn òun ni ẹni tí gbogbo àwọn ìjọ yàn pé kí ó máa bá wa kiri nípa iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ tí à ń ṣe fún ògo Oluwa ati láti fi ìtara wa hàn.

20 À ń ṣe èyí kí ẹnikẹ́ni má baà rí nǹkan wí sí wa nípa ọ̀nà tí à ń gbà ṣe ètò ti ẹ̀bùn yìí.

21 Nítorí ète wa dára lójú Oluwa, ó sì dára lójú àwọn eniyan pẹlu.

22 A tún rán arakunrin wa tí a ti dánwò ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà ní ti ìtara rẹ̀ pé kí ó bá wọn wá. Nisinsinyii ó túbọ̀ ní ìtara pupọ nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé yín pupọ.

23 Ní ti Titu, ẹlẹgbẹ́ mi ati alábàáṣiṣẹ́ mi ni ninu ohun tí ó kàn yín. Ní ti àwọn arakunrin wa, òjíṣẹ́ àwọn ìjọ ni wọ́n, Ògo Kristi sì ni wọ́n.

24 Nítorí náà ẹ fi ìfẹ́ yín hàn sí wọn. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òtítọ́ ni àwọn nǹkan tí a sọ fún wọn, tí a sì fi ọwọ́ rẹ̀ sọ̀yà nípa yín. Ẹ jẹ́ kí ó hàn sí gbogbo àwọn ìjọ bẹ́ẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13