1 Nítorí èyí, níwọ̀n ìgbà tí ó wu Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ láti fi iṣẹ́ yìí fún wa ṣe, ọkàn wa kò rẹ̀wẹ̀sì.
2 A ti kọ àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ tíí máa ti eniyan lójú sílẹ̀. A kò hùwà ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni a kò yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. Ṣugbọn ọ̀nà tí a fi gba iyì ninu ẹ̀rí-ọkàn eniyan ati níwájú Ọlọrun ni pé à ń fi òtítọ́ hàn kedere.
3 Ṣugbọn tí ìyìn rere wa bá ṣókùnkùn, àwọn tí yóo ṣègbé ni ó ṣókùnkùn sí.
4 Àwọn oriṣa ayé yìí ni wọ́n fọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lójú, tí ọkàn wọn kò fi lè gbàgbọ́. Èyí ni kò jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ ìyìn rere Kristi, tí ó lógo, kí ó tàn sí wọn lára; àní, Kristi tíí ṣe àwòrán Ọlọrun.
5 Nítorí kì í ṣe nípa ara wa ni à ń waasu. Ẹni tí à ń waasu rẹ̀ ni Jesu Kristi pé òun ni Oluwa. Iranṣẹ yín ni a jẹ́, nítorí ti Kristi.
6 Nítorí Ọlọrun tí ó ní kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn, òun ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn wa, kí ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọrun lè tàn sí wa ní ojú Kristi.
7 Ṣugbọn bí ìkòkò amọ̀ ni àwa tí ìṣúra yìí wà ninu wa rí, kí ó lè hàn gbangba pé Ọlọrun ni ó ní agbára tí ó tóbi jùlọ, kì í ṣe àwa.
8 A ní oríṣìíríṣìí ìṣòro, ṣugbọn wọn kò wó wa mọ́lẹ̀; ọkàn wa ń dààmú, ṣugbọn a kò ṣe aláìní ìrètí.
9 Àwọn eniyan ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣugbọn Ọlọrun kò fi wá sílẹ̀. Wọ́n gbé wa ṣubú, ṣugbọn wọn kò lè pa wá.
10 À ń ru ikú Jesu káàkiri lára wa nígbà gbogbo, kí ìyè Jesu lè hàn lára wa.
11 Nítorí pé nígbà gbogbo ni à ń fi ẹ̀mí wa wéwu nítorí Jesu, níwọ̀n ìgbà tí a wà láàyè, kí ìyè Jesu lè hàn ninu ẹran-ara wa tí yóo di òkú.
12 Ó wá jẹ́ pé ikú ní ń ṣiṣẹ́ ninu wa, nígbà tí ìyè ń ṣiṣẹ́ ninu yín.
13 Àkọsílẹ̀ kan sọ pé, “Mo gbàgbọ́, nítorí náà ni mo fi sọ̀rọ̀.” Nígbà tí ó ti jẹ́ pé a ní ẹ̀mí igbagbọ kan náà, àwa náà gbàgbọ́, nítorí náà ni a fi ń sọ̀rọ̀.
14 A mọ̀ pé ẹni tí ó jí Oluwa Jesu dìde yóo jí àwa náà dìde pẹlu Jesu, yóo wá mú àwa ati ẹ̀yin wá sí iwájú rẹ̀.
15 Nítorí tiyín ni gbogbo èyí, kí oore-ọ̀fẹ́ lè máa pọ̀ sí i fún ọpọlọpọ eniyan, kí ọpẹ́ yín lè máa pọ̀ sí i fún ògo Ọlọrun.
16 Nítorí náà ni a kò fi sọ ìrètí nù. Nítorí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ara wa ti òde ń bàjẹ́, ṣugbọn ara wa ti inú ń di titun sí i lojoojumọ.
17 Ìjìyà wa mọ níwọ̀n, ati pé fún àkókò díẹ̀ ni. Àyọrísí rẹ̀ ni ògo tí ó pọ̀ pupọ, tí yóo wà títí, tí ó sì pọ̀ ju ìyà tí à ń jẹ lọ.
18 Kì í ṣe àwọn nǹkan tí a lè fi ojú rí ni a tẹjúmọ́, bíkòṣe àwọn nǹkan tí a kò lè fi ojú rí. Nítorí àwọn nǹkan tí yóo wà fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn nǹkan tí a lè fi ojú rí. Àwọn nǹkan tí a kò lè fi ojú rí ni yóo wà títí laelae.