1 Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́, nígbà tí ẹ ti ní àwọn ìlérí yìí, ẹ wẹ gbogbo ìdọ̀tí kúrò ní ara ati ẹ̀mí yín. Ẹ ya ara yín sí mímọ́ patapata pẹlu ìbẹ̀rù Ọlọrun.
2 Ẹ fi wá sọ́kàn. A kò ṣẹ ẹnikẹ́ni. A kò ba ẹnikẹ́ni jẹ́. A kò sì rẹ́ ẹnikẹ́ni jẹ.
3 Kì í ṣe pé mò ń fi èyí ba yín wí. Nítorí, bí mo ti sọ ṣáájú, ẹ ṣe ọ̀wọ́n fún wa tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé bí ó bá kan ti ikú, kí á jọ kú ni, bí ó bá sì jẹ́ ti ìyè, kí á jọ wà láàyè ni.
4 Ọkàn mi balẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yín. Mò ń fi ọwọ́ yín sọ̀yà. Mò ti ní ìtùnú kíkún. Ninu gbogbo ìpọ́njú wa, mo ní ayọ̀ lọpọlọpọ.
5 Nígbà tí a dé Masedonia, ọkàn wa kò balẹ̀ rárá. Wahala ni lọ́tùn-ún lósì, ìjà lóde, ẹ̀rù ninu.
6 Ṣugbọn Ọlọrun tí ń tu àwọn tí ọkàn wọn bá rẹ̀wẹ̀sì ninu, ti tù wá ninu nígbà tí Titu dé.
7 Kì í sìí ṣe ti dídé tí ó dé nìkan ni, ṣugbọn ó ròyìn fún wa, gbogbo bí ẹ ti dá a lọ́kàn le ati gbogbo akitiyan yín lórí wa, bí ọkàn yín ti bàjẹ́ tó fún ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ati bí ẹ ti ní ìtara tó fún mi. Èyí mú kí inú mi dùn pupọ.
8 Bí ó bá jẹ́ pé ìwé tí mo kọ bà yín ninu jẹ́, n kò kábàámọ̀ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti kọ́ kábàámọ̀ pé ìwé náà bà yín lọ́kàn jẹ́ fún ìgbà díẹ̀,
9 ṣugbọn nisinsinyii mo láyọ̀. Kì í ṣe nítorí pé ó bà yín lọ́kàn jẹ́, ṣugbọn nítorí pé bíbà tí ó bà yín lọ́kàn jẹ́ ni ó jẹ́ kí ẹ ronupiwada. Nítorí ẹ farada ìbànújẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti fẹ́, kí ẹ má baà pàdánù nítorí ohun tí a ṣe.
10 Ìbànújẹ́ tí eniyan bà faradà gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti fẹ́ a máa mú kí eniyan ronupiwada kí ó sì rí ìgbàlà, tí kò ní àbámọ̀ ninu. Ṣugbọn tí eniyan bá kàn ní ìbànújẹ́ lásán, ikú ni àyọrísí rẹ̀.
11 Ṣé ẹ wá rí i bí ìbànújẹ́ tí ẹ faradà gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti fẹ́, ti yọrí sí fun yín? Ó mú kí ẹ fi ìtara mú ọ̀rọ̀ náà, kí ẹ sì jà fún ara yín. Ó mú kí inú bi yín sí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó mú ìbẹ̀rù wá sọ́kàn yín. Ó mú kí ẹ ṣe aájò mi. Ó mú kí ẹ ní ìtara. Ó mú kí ẹ rí i pé ẹ ṣe ẹ̀tọ́ ninu ọ̀ràn náà. Ní gbogbo ọ̀nà ẹ ti fihàn pé ọwọ́ yín mọ́ ninu ọ̀ràn náà.
12 Nígbà tí mo kọ ìwé tí mo kọ́ kọ, kì í ṣe nítorí ti ẹni tí ó ṣe àìdára, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ti ẹni tí wọ́n ṣe àìdára sí. Ṣugbọn mo kọ ọ́ kí ìtara yín lè túbọ̀ hàn níwájú Ọlọrun.
13 Ìdí rẹ̀ nìyí tí a fi ní ìtùnú.Lẹ́yìn pé a ní ìtùnú, a tún ní ayọ̀ pupọ nígbà tí a rí bí ayọ̀ Titu ti pọ̀ tó, nítorí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ láàrin gbogbo yín.
14 Nítorí bí mo bá ti sọ ohunkohun nípa yín, tí mo sì ti fi ọwọ́ yín sọ̀yà, ẹ kò dójú tì mí. Ṣugbọn bí ó ti jẹ́ pé òtítọ́ ni gbogbo nǹkan tí a ti sọ fun yín, bẹ́ẹ̀ náà ni ọwọ́ yín tí a fi sọ̀yà fún Titu jẹ́ òtítọ́.
15 Inú Titu dùn si yín lọpọlọpọ nígbà tí ó ranti bí gbogbo yín ti múra láti ṣe ohun tí ó sọ fun yín ati bí ẹ ti gbà á pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì.
16 Mo láyọ̀ pé mo lè gbẹ́kẹ̀lé yín ninu ohun gbogbo.