Kọrinti Keji 6 BM

1 Gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀, à ń bẹ̀ yín pé kí ẹ má ṣe jẹ́ kí gbígbà tí ẹ gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun jẹ́ lásán.

2 Nítorí Ọlọrun sọ pé,“Mo gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ nígbà tí o bá ojurere mi pàdé;mo ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ọjọ́ ìgbàlà.”Ìsinsìnyìí ni àkókò ojurere Ọlọrun. Òní ni ọjọ́ ìgbàlà.

3 A kò fi ohun ìkọsẹ̀ kankan siwaju ẹnikẹ́ni, kí àwọn eniyan má baà rí wí sí iṣẹ́ wa.

4 Ṣugbọn ninu gbogbo nǹkan, à ń fi ara wa sípò àyẹ́sí gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ Ọlọrun. A ti fara da ọpọlọpọ nǹkan ní àkókò inúnibíni, ninu ìdààmú, ati ninu ìṣòro;

5 nígbà tí wọ́n nà wá ati nígbà tí a wà lẹ́wọ̀n, ní àkókò ìrúkèrúdò ati ní àkókò tí iṣẹ́ wọ̀ wá lọ́rùn, tí à ń pa ebi mọ́nú.

6 À ń ṣiṣẹ́ pẹlu ọkàn kan; pẹlu ọgbọ́n ati sùúrù, pẹlu inú rere ati ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, pẹlu ìfẹ́ tí kò lẹ́tàn.

7 À ń ṣe iṣẹ́ wa pẹlu òtítọ́ inú ati agbára Ọlọrun. A mú ohun ìjà òdodo lọ́wọ́ ọ̀tún ati lọ́wọ́ òsì.

8 Bí a ti ń gba ọlá, bẹ́ẹ̀ ni à ń gba ìtìjú. Bí a ti ń gba èébú, bẹ́ẹ̀ ni à ń gba ìyìn. Àwọn ẹlòmíràn kà wá sí ẹlẹ́tàn, bẹ́ẹ̀ sì ni olóòótọ́ ni wá.

9 Ìwà wa kò yé àwọn eniyan, sibẹ gbogbo eniyan ni ó mọ̀ wá. A dàbí ẹni tí ń kú lọ, sibẹ a tún wà láàyè. A ti ní ìrírí ìtọ́ni pẹlu ìjìyà, sibẹ ìjìyà yìí kò pa wá.

10 A ní ìrírí ìbànújẹ́ nígbà gbogbo, sibẹ à ń yọ̀. A jẹ́ aláìní, sibẹ a ti sọ ọpọlọpọ di ọlọ́rọ̀. A dàbí àwọn tí kò ní nǹkankan, sibẹ a ní ohun gbogbo.

11 A ti sọ òtítọ́ inú wa fun yín, ẹ̀yin ará Kọrinti. Ọkàn wa ṣípayá si yín.

12 Kò sí ohun kan ní ọkàn wa si yín. Bí ohun kan bá wà, a jẹ́ pé ní ọkàn tiyín ni.

13 Mò ń ba yín sọ̀rọ̀ bí ọmọ. Ohun tí ó yẹ yín ni pé kí ẹ ṣí ọkàn yín payá sí wa.

Ilé Ọlọrun Alààyè

14 Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ àwọn alaigbagbọ. Nítorí ìrẹ́pọ̀ wo ni ó wà láàrin ìwà òdodo ati aiṣododo? Tabi, kí ni ó pa ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn pọ̀?

15 Báwo ni Kristi ti ṣe lè fi ohùn ṣọ̀kan pẹlu Èṣù? Kí ni ìbá pa onigbagbọ ati alaigbagbọ pọ̀?

16 Kí ni oriṣa ń wá ninu ilé Ọlọrun? Nítorí ilé Ọlọrun alààyè ni àwa jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ, pé,“N óo máa gbé ààrin wọn,n óo máa káàkiri ní ààrin wọn.N óo jẹ́ Ọlọrun wọn,wọn yóo sì jẹ́ eniyan mi.

17 Nítorí náà ẹ jáde kúrò láàrin wọn,ẹ ya ara yín sọ́tọ̀, ni Oluwa wí.Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́,kí n lè gbà yín.

18 N óo jẹ́ baba fun yín,ẹ̀yin náà óo sì jẹ́ ọmọ fún mi,lọkunrin ati lobinrin yín.Èmi Oluwa Olodumare ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13