Kọrinti Kinni 6 BM

Onigbagbọ Ń Pe Ara Wọn Lẹ́jọ́ Níwájú Àwọn Alaigbagbọ

1 Kí ló dé tí ẹni tí ó bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkejì rẹ̀ fi ń gbé ẹjọ́ lọ siwaju àwọn alaigbagbọ?

2 Àbí ẹ kò mọ̀ pé àwọn onigbagbọ ni yóo ṣe ìdájọ́ ayé? Nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ̀yin ni ẹ óo ṣe ìdájọ́ ayé, ó ti wá jẹ́ tí ẹ kò fi lè ṣe ìdájọ́ àwọn tí ó kéré jùlọ?

3 Àbí ẹ kò mọ̀ pé àwa onigbagbọ ni yóo ṣe ìdájọ́ àwọn angẹli! Mélòó-mélòó wá ni àwọn nǹkan ti ayé yìí?

4 Bí ẹ bá ní ẹ̀sùn nípa nǹkan ti ayé, kí ló dé ti ẹ fi ń pe àwọn alaigbagbọ tí kò lẹ́nu ninu ìjọ láti máa jókòó lórí ọ̀rọ̀ yín?

5 Kí ojú baà lè tì yín ni mo fi ń sọ̀rọ̀ báyìí! Ṣé kò wá sí ẹnikẹ́ni láàrin yín tí ó gbọ́n tó láti dá ẹjọ́ fún ẹnìkan ati arakunrin rẹ̀ ni?

6 Dípò kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀, onigbagbọ ń pe onigbagbọ lẹ́jọ́ níwájú àwọn alaigbagbọ!

7 Nǹkankan kù díẹ̀ kí ó tó nípa igbagbọ yín. Òun ni ó mú kí ẹ máa ní ẹ̀sùn sí ara yín. Kí ni kò jẹ́ kí olukuluku yín kúkú máa gba ìwọ̀sí? Kí ni kò jẹ́ kí ẹ máa gba ìrẹ́jẹ?

8 Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni ẹ̀ ń fi ìwọ̀sí kan ara yín tí ẹ̀ ń rẹ́ ara yín jẹ, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ onigbagbọ!

9 Àbí ẹ kò mọ̀ pé kò sí alaiṣododo kan tí yóo jogún ìjọba Ọlọrun? Ẹ má tan ara yín jẹ, kò sí àwọn oníṣekúṣe, tabi àwọn abọ̀rìṣà, àwọn àgbèrè tabi àwọn oníbàjẹ́, tabi àwọn tí ó ń bá ọkunrin lòpọ̀ bí obinrin;

10 àwọn olè tabi àwọn olójúkòkòrò, àwọn ọ̀mùtí-para tabi àwọn abanijẹ́, tabi àwọn oníjìbìtì, tí yóo jogún ìjọba Ọlọrun.

11 Àwọn mìíràn wà ninu yín tí wọn ń hu irú ìwà báyìí tẹ́lẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti wẹ̀ yín mọ́, a ti yà yín sọ́tọ̀, a ti da yín láre nípa orúkọ Oluwa Jesu Kristi ati nípa Ẹ̀mí Ọlọrun wa.

Ẹ Fi Ara Yín Yin Ọlọrun

12 Ẹnìkan lè sọ pé, “Kò sí ohun tí kò tọ̀nà fún mi láti ṣe.” Bẹ́ẹ̀ ni, ṣugbọn kì í ṣe gbogbo nǹkan tí o lè ṣe ni yóo ṣe ọ́ ní anfaani. Kò sí ohun tí kò tọ̀nà fún mi láti ṣe, ṣugbọn n kò ní jẹ́ kí ohunkohun jọba lé mi lórí.

13 Oúnjẹ wà fún ikùn, ikùn sì wà fún oúnjẹ. Ṣugbọn ati oúnjẹ ati ikùn ni Ọlọrun yóo parun. Ara kò wà fún ṣíṣe àgbèrè bíkòṣe pé kí á lò ó fún Oluwa. Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wà fún ara.

14 Bí Ọlọrun ti jí Oluwa dìde kúrò ninu òkú, bẹ́ẹ̀ ní yóo jí àwa náà pẹlu agbára rẹ̀.

15 Àbí ẹ kò mọ̀ pé ẹ̀yà ara Kristi ni àwọn ẹ̀yà ara yín jẹ́? Ṣé kí a wá sọ ẹ̀yà ara Kristi di ẹ̀yà ara àgbèrè ni? Ọlọrun má jẹ̀ẹ́!

16 Àbí ẹ kò mọ̀ pé ẹni tí ó bá alágbèrè lòpọ̀ ti di ara kan pẹlu rẹ̀? Ìwé Mímọ́ sọ pé. “Àwọn mejeeji yóo di ara kan.”

17 Ṣugbọn ẹni tí ó bá ní ìdàpọ̀ pẹlu Oluwa di ọ̀kan pẹlu rẹ̀ ninu ẹ̀mí.

18 Ẹ sá fún ìwà àgbèrè. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí eniyan lè máa dá kò kan ara olúwarẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun tìkararẹ̀.

19 Àbí, ẹ kò mọ̀ pé ara yín ni ibùgbé Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó wà ninu yín, tí ẹ gbà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun? Ati pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ ni ara yín?

20 Iyebíye ni Ọlọrun rà yín, nítorí náà, ẹ fi ara yín yin Ọlọrun.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16