3 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé Kristi ni orí fún olukuluku ọkunrin, ọkunrin ni orí fún obinrin, Ọlọrun wá ni orí Kristi.
4 Ọkunrin tí ó bá ń gbadura tabi tí ó bá ń waasu tí ó bo orí fi àbùkù kan orí rẹ̀.
5 Ṣugbọn obinrin tí ó bá ń gbadura tabi tí ó bá ń waasu láì bo orí rẹ̀ fi àbùkù kan orí rẹ̀. Ó dàbí kí ó kúkú fá orí rẹ̀.
6 Nítorí bí obinrin kò bá bo orí, kí ó kúkú gé irun rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ṣugbọn tí ó bá jẹ́ ìtìjú fún obinrin láti gé irun rẹ̀ mọ́lẹ̀ tabi láti fá orí rẹ̀ a jẹ́ pé ó níláti bo orí rẹ̀.
7 Nítorí kò tọ́ kí ọkunrin bo orí rẹ̀, nítorí àwòrán ati ògo Ọlọrun ni. Ṣugbọn ògo ọkunrin ni obinrin.
8 Nítorí ọkunrin kò wá láti ara obinrin; obinrin ni ó wá láti ara ọkunrin.
9 Ati pé a kò dá ọkunrin nítorí obinrin, obinrin ni a dá nítorí ọkunrin.