Kọrinti Kinni 14:22-28 BM

22 Àwọn èdè àjèjì yìí kì í ṣe àmì fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bíkòṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́.

23 Nítorí náà, nígbà tí gbogbo ìjọ bá péjọ pọ̀ sí ibìkan náà, tí gbogbo yín bá ń fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, tí àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ, tabi àwọn alaigbagbọ bá wọlé, ǹjẹ́ wọn kò ní sọ pé ẹ̀ ń ṣiwèrè ni?

24 Ṣugbọn bí gbogbo yín bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, bí ẹnìkan tí ó jẹ́ alaigbagbọ tabi ẹnìkan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ bá wọlé, yóo gbọ́ ohun tí ó jẹ́ ìbáwí ati ohun tí yóo mú un yẹ ara rẹ̀ wò ninu ọ̀rọ̀ tí ẹ̀ ń sọ.

25 Àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ ọkàn rẹ̀ yóo hàn kedere, ni yóo bá dojúbolẹ̀, yóo sì júbà Ọlọrun. Yóo sọ pé, “Dájúdájú Ọlọrun wà láàrin yín.”

26 Ará, kí ni kókó ohun tí à ń sọ? Nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀, bí ẹnìkan bá ní orin, tí ẹnìkan ní ẹ̀kọ́, tí ẹnìkan ní ìfihàn, tí ẹnìkan ní èdè àjèjì, tí ẹnìkan ní ìtumọ̀ fún èdè àjèjì, ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ohun gbogbo fún ìdàgbà ìjọ.

27 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, kí wọ́n má ju meji lọ, tabi ó wá pọ̀jù patapata, kí wọ́n jẹ́ mẹta. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ni kí wọ́n máa sọ̀rọ̀, kí ẹnìkan sì máa túmọ̀ ohun tí wọn ń sọ.

28 Bí kò bá sí ẹni tí yóo ṣe ìtumọ̀, kí ẹni tí ó fẹ́ fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀ dákẹ́ ninu ìjọ. Kí ó máa fi èdè àjèjì bá ara rẹ̀ ati Ọlọrun sọ̀rọ̀.