53 Nítorí ara tíí bàjẹ́ yìí níláti gbé ara tí kì í bàjẹ́ wọ̀; ara tí yóo kú yìí níláti gbé ara tí kì í kú wọ̀.
54 Nígbà tí ara tíí bàjẹ́ bá ti gbé ara tí kì í bàjẹ́ wọ̀ tán, tí ara tí yóo kú bá sì ti gbé ara tí kì í kú wọ̀, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ tí a ti kọ sílẹ̀ yóo wá ṣẹ pé,“A ti gbé ikú mì,a sì ti ṣẹgun.”
55 “Ikú, oró rẹ dà?Isà òkú, ìṣẹ́gun rẹ dà?”
56 Ẹ̀ṣẹ̀ ni ó fún ikú lóró. Òfin ni ó fún ẹ̀ṣẹ̀ lágbára.
57 Ṣugbọn ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó fún wa ní ìṣẹ́gun nípasẹ̀ Oluwa wa Jesu Kristi.
58 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ẹ dúró gbọningbọnin, láì yẹsẹ̀. Ẹ tẹra mọ́ iṣẹ́ Oluwa nígbà gbogbo. Ẹ kúkú ti mọ̀ pé làálàá tí ẹ̀ ń ṣe níbi iṣẹ́ Oluwa kò ní jẹ́ lásán.