1 A gbọ́ dájúdájú pé ìwà àgbèrè wà láàrin yín, irú èyí tí kò tilẹ̀ sí láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. A gbọ́ pé ẹnìkan ń bá iyawo baba rẹ̀ lòpọ̀!
2 Dípò èyí tí ọkàn yín ìbá fi bàjẹ́, tí ẹ̀ bá sì yọ ẹni tí ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kúrò láàrin yín, ẹ wá ń ṣe fáàrí!
3-4 Bí èmi alára kò tilẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín mo wà lọ́dọ̀ yín ninu ẹ̀mí. Mo ti ṣe ìdájọ́ ẹni tí ó ṣe nǹkan bẹ́ẹ̀ ní orúkọ Jesu Oluwa bí ẹni pé mo wà lọ́dọ̀ yín. Nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀, tí ẹ̀mí mi sì wà pẹlu yín, pẹlu agbára Oluwa wa Jesu,
5 ẹ fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ fún Satani, kí Satani lè pa ara rẹ̀ run, kí á lè gba ẹ̀mí rẹ̀ là ní ọjọ́ ìfarahàn Oluwa wa.
6 Fáàrí tí ẹ̀ ń ṣe kò dára! Ẹ kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ni ó ń mú burẹdi wú sókè?
7 Ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò, kí ẹ lè dàbí burẹdi titun, ẹ óo wá di burẹdi titun ti kò ní ìwúkàrà ninu. Nítorí a ti fi Kristi ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá wa rúbọ.
8 Nítorí náà ẹ jẹ́ kí á ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá wa, kì í ṣe burẹdi tí ó ní ìwúkàrà àtijọ́ ti ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú ni kí á fi ṣe é, ṣugbọn pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, burẹdi ìwà mímọ́ ati òtítọ́.