6 ṣugbọn ní tiwa, Ọlọrun kan ni ó wà, tíí ṣe Baba, lọ́dọ̀ ẹni tí gbogbo nǹkan ti wá, ati lọ́dọ̀ ẹni tí àwa ń lọ. Oluwa kan ni ó wà. Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí a dá gbogbo nǹkan, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá àwa náà.
7 Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó ní ìmọ̀ yìí. Nítorí àwọn mìíràn wà tí èèwọ̀ nípa ìbọ̀rìṣà ti mọ́ lára tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé, bí wọn bá jẹ irú oúnjẹ yìí, bí ìgbà tí wọn ń bọ̀rìṣà ni. Nítorí wọn kò ní ẹ̀rí ọkàn tí ó lágbára, jíjẹ oúnjẹ bẹ́ẹ̀ jẹ́ àbùkù fún wọn.
8 Kì í ṣe oúnjẹ ni yóo mú wa dé iwájú Ọlọrun. Bí a kò bá jẹ, kò bù wá kù, bí a bá sì jẹ, kò mú kí á sàn ju bí a ti rí tẹ́lẹ̀ lọ.
9 Ṣugbọn ẹ ṣọ́ra kí òmìnira yín má di ohun tí yóo gbé àwọn aláìlera ṣubú.
10 Nítorí bí ẹnìkan tí ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ kò bá lágbára bá rí ìwọ tí o ní ìmọ̀ tí ò ń jẹun ní ilé oriṣa, ǹjẹ́ òun náà kò ní fi ìgboyà wọ inú ilé oriṣa lọ jẹun?
11 Àyọrísí rẹ̀ ni pé ìmọ̀ tìrẹ mú ìparun bá ẹni tí ó jẹ́ aláìlera, arakunrin tí Kristi ti ìtorí tirẹ̀ kú.
12 Ẹ̀ ń fi bẹ́ẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí àwọn arakunrin yín tí ó jẹ́ aláìlera, ẹ̀ ń dá ọgbẹ́ sí ọkàn wọn, ẹ sì ń fi bẹ́ẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí Kristi.