11 Nígbà tí a fúnrúgbìn nǹkan ẹ̀mí fun yín, ṣé ó pọ̀jù pé kí á kórè nǹkan ti ara lọ́dọ̀ yín?
12 Bí àwọn ẹlòmíràn bá ní ẹ̀tọ́ láti jẹ lára yín, ṣé ẹ̀tọ́ tiwa kò ju tiwọn lọ?Ṣugbọn a kò lo anfaani tí a ní yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀ à ń fara da ohun gbogbo kí á má baà fa ìdínà fún ìyìn rere Kristi.
13 Ẹ kò mọ̀ pé àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ninu Tẹmpili a máa jẹ lára ẹbọ, ati pé àwọn tí ń ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ ìrúbọ a máa pín ninu nǹkan ìrúbọ tí ó wà lórí pẹpẹ?
14 Bẹ́ẹ̀ gan-an ni Oluwa pàṣẹ pé kí àwọn tí ó ń waasu ìyìn rere máa jẹ láti inú iṣẹ́ ìyìn rere.
15 Ṣugbọn n kò lo anfaani yìí rí. Kì í ṣe pé kí n lè lo anfaani yìí ni mo ṣe ń sọ ohun tí mò ń sọ yìí. Nítorí ó yá mi lára kí ń kúkú kú jù pé kí ẹnikẹ́ni wá sọ ọ̀nà ìṣògo mi di asán lọ.
16 Nítorí bí mo bá ń waasu ìyìn rere, kì í ṣe ohun tí mo lè máa fi ṣògo. Nítorí dandan ni ó jẹ́ fún mi. Bí n kò bá waasu ìyìn rere, mo gbé!
17 Nítorí bí ó bá jẹ́ pé èmi fúnra mi ni mo yàn láti máa ṣe iṣẹ́ yìí, mo ní ẹ̀tọ́ láti retí èrè níbẹ̀. Ṣugbọn tí ó bá jẹ́ dandan ni mo fi ń ṣe é, iṣẹ́ ìríjú tí a fi sí ìtọ́jú mi ni.