3 Máa fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lojoojumọ.
4 Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá,nítorí àwa náà ń dáríjì gbogbo ẹni tí ó bá jẹ wá ní gbèsè.Má ṣe fà wá sinu ìdánwò.’ ”
5 Ó tún fi kún un fún wọn pé, “Bí ẹnìkan ninu yín bá ní ọ̀rẹ́ kan, tí ó wá lọ sọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ yìí ní ọ̀gànjọ́ òru, tí ó sọ fún un pé, ‘Ọ̀rẹ́ mi, yá mi ní burẹdi mẹta,
6 nítorí ọ̀rẹ́ mi kan ti ìrìn àjò dé bá mi, n kò sì ní oúnjẹ tí n óo fún un’;
7 kí ọ̀rẹ́ náà wá ti inú ilé dáhùn pé, ‘Má yọ mí lẹ́nu. Mo ti ti ìlẹ̀kùn, àwọn ọmọ mi sì wà lórí ẹní pẹlu mi, n kò lè tún dìde kí n fún ọ ní nǹkankan mọ́.’
8 Mò ń sọ fun yín pé, bí kò tilẹ̀ fẹ́ dìde kí ó fún ọ nítorí o jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣugbọn nítorí tí o kò tijú láti wá kan ìlẹ̀kùn mọ́ ọn lórí lóru, yóo dìde, yóo fún ọ ní ohun tí o nílò.
9 “Bákan náà mo sọ fun yín, ẹ bèèrè, a óo fi fun yín; ẹ wá kiri, ẹ óo rí; ẹ kanlẹ̀kùn, a óo sì ṣí i fun yín.