1 Ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n ti kọ ìròyìn lẹ́sẹẹsẹ, nípa ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ láàrin wa;
2 àwọn tí nǹkan wọnyi ṣojú wọn, tí wọ́n sì sọ fún wa.
3 Mo ti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí ohun gbogbo fínnífínní. Èmi náà wá pinnu láti kọ ìwé sí ọ lẹ́sẹẹsẹ, ọlọ́lá jùlọ, Tiofilu,
4 kí o lè mọ òtítọ́ àwọn nǹkan tí wọ́n kọ́ ọ.
5 Ní àkókò Hẹrọdu, ọba Judia, alufaa kan wà tí ń jẹ́ Sakaraya, ní ìdílé Abiya. Orúkọ iyawo rẹ̀ ni Elisabẹti, láti inú ìdílé Aaroni.
6 Àwọn mejeeji ń rìn déédé níwájú Ọlọrun, wọ́n ń pa gbogbo àwọn àṣẹ ati ìlànà Oluwa mọ́ láì kùnà.
7 Ṣugbọn wọn kò ní ọmọ, nítorí pé Elisabẹti yàgàn. Àwọn mejeeji ni wọ́n sì ti di arúgbó.
8 Nígbà tí ó yá, ó kan ìpín àwọn Sakaraya láti wá ṣe iṣẹ́ alufaa níwájú Ọlọrun ninu Tẹmpili.
9 Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn alufaa, Sakaraya ni ìbò mú láti sun turari ninu iyàrá Tẹmpili Oluwa.
10 Gbogbo àwọn eniyan ń gbadura lóde ní àkókò tí ó ń sun turari.
11 Angẹli Oluwa kan bá yọ sí i, ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún pẹpẹ turari.
12 Nígbà tí Sakaraya rí i, ó ta gìrì, ẹ̀rù bà á.
13 Ṣugbọn angẹli náà sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sakaraya, nítorí pé adura rẹ ti gbà. Elisabẹti iyawo rẹ yóo bí ọmọkunrin kan fún ọ, o óo pe orúkọ rẹ̀ ní Johanu.
14 Ayọ̀ yóo kún ọkàn rẹ. Ọpọlọpọ eniyan ni yóo bá ọ yọ̀ nígbà tí ẹ bá bí ọmọ náà.
15 Ọmọ náà yóo jẹ́ ẹni ńlá níwájú Oluwa. Kò gbọdọ̀ mu ọtíkọ́tí, ìbáà jẹ́ líle tabi èyí tí kò le. Yóo kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ láti ìgbà tí ó bá tí wà ninu ìyá rẹ̀;
16 ọpọlọpọ àwọn ọmọ Israẹli ni yóo sì yipada sí Oluwa Ọlọrun wọn.
17 Òun ni yóo ṣáájú Oluwa pẹlu ẹ̀mí Elija ati agbára rẹ̀. Yóo mú kí àwọn baba wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu àwọn ọmọ wọn. Yóo yí àwọn alágídí ọkàn pada sí ọ̀nà rere. Yóo sọ àwọn eniyan di yíyẹ lọ́dọ̀ Oluwa.”
18 Sakaraya bi angẹli náà pé, “Báwo ni n óo ti ṣe mọ̀? Nítorí pé mo ti di arúgbó; iyawo mi alára náà sì ti di àgbàlagbà.”
19 Angẹli náà dá a lóhùn pé, “Geburẹli ni orúkọ mi, èmi ni mo máa ń dúró níwájú Ọlọrun. Ọlọrun ló rán mi láti bá ọ sọ̀rọ̀, ati láti sọ nǹkan ayọ̀ yìí fún ọ.
20 Nítorí pé ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́, o óo ya odi, o kò ní lè sọ̀rọ̀ títí ọjọ́ tí gbogbo nǹkan wọnyi yóo fi ṣẹlẹ̀. Gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ yìí yóo ṣẹ nígbà tí ó bá yá.”
21 Àwọn eniyan ti ń retí Sakaraya. Ẹnu yà wọ́n pé ó pẹ́ ninu iyàrá Tẹmpili.
22 Nígbà tí ó jáde, kò lè bá wọn sọ̀rọ̀. Wọ́n sì mọ̀ pé ó ti rí ìran ninu iyàrá Tẹmpili ni. Ó yadi, ọwọ́ ni ó fi ń ṣe àpèjúwe fún wọn.
23 Nígbà tí ó parí àkókò tí yóo fi ṣiṣẹ́ alufaa ninu Tẹmpili, ó pada lọ sí ilé rẹ̀.
24 Lẹ́yìn náà, Elisabẹti lóyún. Ó bá fi ara pamọ́ fún oṣù marun-un. Ó ní,
25 “Oluwa ni ó ṣe èyí fún mi. Ó ti fi ojú àánú wò mí, ó sì ti mú ohun tí ó jẹ́ ẹ̀gàn fún mi lójú eniyan kúrò.”
26 Ní oṣù kẹfa, Ọlọrun rán angẹli Geburẹli lọ sí ìlú kan ní Galili tí wọn ń pè ní Nasarẹti.
27 Ọlọrun rán an lọ sí ọ̀dọ̀ wundia kan tí ó jẹ́ iyawo àfẹ́sọ́nà ọkunrin kan tí ń jẹ́ Josẹfu, ti ìdílé Dafidi. Wundia náà ń jẹ́ Maria.
28 Angẹli náà wọlé tọ Maria lọ, ó kí i, ó ní “Alaafia ni fún ọ! Ìwọ ẹni tí Ọlọrun kọjú sí ṣe ní oore, Oluwa wà pẹlu rẹ.”
29 Nígbà tí Maria gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ara rẹ̀ kò balẹ̀, ó ń rò lọ́kàn rẹ̀ pé, irú kíkí wo nìyí?
30 Angẹli náà sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, Maria, nítorí o ti bá ojurere Ọlọrun pàdé.
31 O óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan, Jesu ni o óo pe orúkọ rẹ̀.
32 Eniyan ńlá ni yóo jẹ́. Ọmọ Ọ̀gá Ògo ni a óo máa pè é. Oluwa Ọlọrun yóo fún un ní ìtẹ́ Dafidi, baba rẹ̀.
33 Yóo jọba lórí ìdílé Jakọbu títí lae, ìjọba rẹ̀ kò ní lópin.”
34 Maria bá bi angẹli náà pé, “Báwo ni yóo ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí n kò tíì mọ ọkunrin?”
35 Angẹli náà dá a lóhùn pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóo tọ̀ ọ́ wá, agbára Ọ̀gá Ògo yóo ṣíji bò ọ́. Nítorí náà Ọmọ Mímọ́ Ọlọrun ni a óo máa pe ọmọ tí ìwọ óo bí.
36 Ati pé Elisabẹti, ìbátan rẹ náà ti lóyún ọmọkunrin kan ní ìgbà ogbó rẹ̀. Ẹni tí wọ́n ti ń pè ní àgàn rí sì ti di aboyún oṣù mẹfa.
37 Nítorí kò sí ohun tí ó ṣòro fún Ọlọrun.”
38 Maria bá dáhùn pé, “Iranṣẹ Oluwa ni mí. Kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Angẹli náà bá fi í sílẹ̀ lọ.
39 Lẹ́yìn náà, Maria múra pẹlu ìwàǹwára, ó lọ sí ìlú Judia kan tí ó wà ní agbègbè orí òkè.
40 Ó wọ inú ilé Sakaraya, ó bá kí Elisabẹti.
41 Bí Elisabẹti ti gbọ́ ohùn Maria, bẹ́ẹ̀ ni ọlẹ̀ sọ ninu rẹ̀; Elisabẹti sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.
42 Ó kígbe sókè, ó ní, “Ibukun Ọlọrun wà lórí rẹ pupọ láàrin àwọn obinrin. Ibukun Ọlọrun sì wà lórí ọmọ inú rẹ.
43 Mo ṣe ṣe oríire tó báyìí, tí ìyá Oluwa mi fi wá sọ́dọ̀ mi?
44 Nítorí bí mo ti gbọ́ ohùn rẹ nígbà tí o kí mi, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ inú mi sọ nítorí ó láyọ̀.
45 Ayọ̀ ń bẹ fún ọ nítorí o gba ohun tí Oluwa ti sọ gbọ́, pé yóo ṣẹ.”
46 Nígbà náà ni Maria sọ pé,“Ọkàn mi gbé Oluwa ga,
47 ẹ̀mí mi yọ̀ sí Ọlọrun, Olùgbàlà mi,
48 nítorí ó ti bojúwo ipò ìrẹ̀lẹ̀ iranṣẹbinrin rẹ̀.Wò ó! Láti ìgbà yìí lọgbogbo ìran ni yóo máa pè mí ní olóríire.
49 Nítorí Olodumare ti ṣe ohun ńlá fún mi,Mímọ́ ni orúkọ rẹ̀;
50 àánú rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìranfún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
51 Ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fi agbára rẹ̀ hàn,ó tú àwọn tí ó gbéraga ninu ọkàn wọn ká.
52 Ó yọ àwọn ìjòyè kúrò lórí oyè,ó gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ga.
53 Ó fi oúnjẹ tí ó dára bọ́ àwọn tí ebi ń pa,ó mú àwọn ọlọ́rọ̀ jáde lọ́wọ́ òfo.
54 Ó ran Israẹli ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́nígbà tí ó ranti àánú rẹ̀,
55 gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí ó ti ṣe fún àwọn baba wa:fún Abrahamu ati fún ìdílé rẹ̀ títí lae.”
56 Maria dúró lọ́dọ̀ Elisabẹti tó bíi oṣù mẹta, ó bá pada lọ sí ilé rẹ̀.
57 Nígbà tí àkókò Elisabẹti tó tí yóo bí, ó bí ọmọkunrin kan.
58 Àwọn aládùúgbò rẹ̀ ati àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ gbọ́ pé Oluwa ti ṣàánú pupọ fún un, wọ́n wá bá a yọ̀.
59 Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹjọ, wọ́n wá láti kọ́ ọmọ náà ní ilà-abẹ́. Wọ́n fẹ́ sọ ọ́ ní Sakaraya, bí orúkọ baba rẹ̀.
60 Ṣugbọn ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Rárá o! Johanu ni a óo máa pè é.”
61 Wọ́n sọ fún un pé, “Kò sí ẹnìkan ninu àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tí ó ń jẹ́ orúkọ yìí.”
62 Wọ́n wá ṣe àpẹẹrẹ sí baba rẹ̀ pé báwo ni ó fẹ́ kí á máa pe ọmọ náà.
63 Ó bá bèèrè fún nǹkan ìkọ̀wé, ó kọ ọ́ pé, “Johanu ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu ya gbogbo eniyan.
64 Lẹsẹkẹsẹ ohùn Sakaraya bá là, okùn ahọ́n rẹ̀ tú, ó bá ń sọ̀rọ̀, ó ń yin Ọlọrun.
65 Ẹ̀rù ńlá ba gbogbo àwọn aládùúgbò wọn. Ìròyìn tàn ká gbogbo agbègbè olókè Judia, wọ́n ń sọ ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀.
66 Gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ń da ọ̀rọ̀ náà rò ninu ọkàn wọn, wọ́n ń sọ pé, “Irú ọmọ wo ni èyí yóo jẹ́?” Nítorí ọwọ́ Oluwa wà lára rẹ̀.
67 Sakaraya, baba ọmọ náà, kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ó bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé,
68 Kí á yin Oluwa Ọlọrun Israẹlinítorí ó ti mú ìrànlọ́wọ́ wá fún àwọn eniyan rẹ̀,ó sì ti dá wọn nídè.
69 Ó ti gbé Olùgbàlà dìde fún waní ìdílé Dafidi, iranṣẹ rẹ̀;
70 gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀ mímọ́,láti ọjọ́ pípẹ́;
71 pé yóo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá waati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ó kórìíra wa;
72 pé yóo fi àánú bá àwọn baba wa lò,ati pé yóo ranti majẹmu rẹ̀ mímọ́
73 gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún Abrahamu baba wa,
74 pé yóo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,ati pé yóo fún wa ní anfaani láti máa sìn ín láì fòyà,
75 pẹlu ọkàn kan ati pẹlu òdodoníwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.
76 “Ìwọ, ọmọ mi,wolii Ọ̀gá Ògo ni a óo máa pè ọ́,nítorí ìwọ ni yóo ṣáájú Oluwa láti palẹ̀ mọ́ dè é,
77 láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn eniyan rẹ̀,nípa ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
78 nítorí àánú Ọlọrun wa,nípa èyí tí oòrùn ìgbàlà fi ràn lé wa lórí láti òkè wá,
79 láti tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn tí ó wà ní òkùnkùnati àwọn tí ó jókòó níbi òjìji ikú,láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà alaafia.”
80 Ọmọ náà ń dàgbà, ó sì ń lágbára sí i lára ati lẹ́mìí. Ilẹ̀ aṣálẹ̀ ni ó ń gbé títí di àkókò tí ó fara han àwọn eniyan Israẹli.