Luku 20 BM

Ìbéèrè Nípa Àṣẹ Tí Jesu Ń Lò

1 Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu Tẹmpili, tí ó ń waasu ìyìn rere fún wọn, àwọn olórí alufaa, àwọn amòfin, ati àwọn àgbà wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

2 Wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa irú àṣẹ tí o fi ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi; ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ yìí?”

3 Ó dá wọn lóhùn pé, “Èmi náà yóo bi yín ní ọ̀rọ̀ kan, ẹ dá mi lóhùn.

4 Ìrìbọmi tí Johanu ń ṣe, láti ọ̀run wá ni, tabi láti ọ̀dọ̀ eniyan?”

5 Wọ́n ń bá ara wọn sọ pé, “Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run ni,’ yóo bi wá pé, ‘Kí ló dé tí ẹ kò fi gbà á gbọ́?’

6 Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ eniyan ni,’ gbogbo àwọn eniyan yóo sọ wá ní òkúta pa, nítorí wọ́n gbà dájú pé wolii ni Johanu.”

7 Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “A kò mọ ibi tí ó ti wá.”

8 Jesu bá sọ fún wọn pé, “Èmi náà kò ní sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi fún yín.”

Òwe Àwọn Alágbàro Kan ati Ọgbà Àjàrà

9 Ó wá pa òwe yìí fún àwọn eniyan. Ó ní, “Ọkunrin kan gbin àjàrà sinu ọgbà kan, ó gba àwọn alágbàro sibẹ, ó bá lọ sí ìrìn àjò. Ó pẹ́ níbi tí ó lọ.

10 Nígbà tí ó yá, ó rán ẹrú rẹ̀ kan sí àwọn alágbàro náà. Ṣugbọn àwọn alágbàro yìí lù ú, wọ́n bá dá a pada ní ọwọ́ òfo.

11 Ọkunrin yìí tún rán ẹrú mìíràn. Àwọn alágbàro yìí tún lù ú, wọ́n fi àbùkù kàn án, wọ́n bá tún dá òun náà pada ní ọwọ́ òfo.

12 Ọkunrin yìí tún rán ẹnìkẹta. Wọ́n tilẹ̀ ṣe òun léṣe ni, ní tirẹ̀, wọ́n bá lé e jáde.

13 Ẹni tí ó ni ọgbà yìí wá rò ninu ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni n óo ṣe o? N óo rán àyànfẹ́ ọmọ mi, bóyá wọn yóo bọlá fún un.’

14 Ṣugbọn nígbà tí àwọn alágbàro yìí rí i, wọ́n bà ara wọn sọ pé, ‘Àrólé rẹ̀ nìyí. Ẹ jẹ́ kí á pa á, kí ogún rẹ̀ lè di tiwa.’

15 Ni wọ́n bá mú un jáde kúrò ninu ọgbà náà, wọ́n bá pa á.“Kí ni ẹni tí ó ni ọgbà náà yóo wá ṣe?

16 Yóo pa àwọn alágbàro wọnyi, yóo sì gbé ọgbà rẹ̀ fún àwọn mìíràn láti tọ́jú.”Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n ní “Ọlọrun má jẹ́!”

17 Jesu bá wò wọ́n lójú, ó ní, “Ǹjẹ́ kí ni ìtumọ̀ àkọsílẹ̀ yìí,‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,òun ni ó di òkúta pataki ní igun ilé.’

18 Bí ẹnikẹ́ni bá ṣubú lu òkúta yìí, olúwarẹ̀ yóo fọ́ yángá-yángá, bí òkúta yìí bá sì bọ́ lu ẹnikẹ́ni, rírẹ́ ni yóo rẹ́ olúwarẹ̀ pẹ́tẹ́pẹ́tẹ́.”

19 Àwọn akọ̀wé ati àwọn olórí alufaa gbèrò láti mú un ní wakati náà, nítorí wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó pa òwe yìí mọ́; ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan.

Owó-Orí fún Kesari

20 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ́ ọ. Wọ́n rán àwọn amí kí wọ́n ṣe bí eniyan rere, kí wọ́n lè ká ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, kí wọn wá fi lé gomina lọ́wọ́, kí gomina dá sẹ̀ría fún un.

21 Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, a mọ̀ pé tààrà ni ò ń sọ̀rọ̀, tí o sì ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́. O kì í wo ojú eniyan kí o tó sọ̀rọ̀. Ṣugbọn pẹlu òtítọ́ ni ò ń kọ́ eniyan ní ọ̀nà Ọlọrun.

22 Ṣé ó tọ́ fún wa láti san owó-orí fún Kesari, àbí kò tọ́?”

23 Ṣugbọn ó ti mọ ẹ̀tàn wọn. Ó sọ fún wọn pé,

24 “Ẹ fi owó fadaka kan hàn mí.” Ó bá bi wọ́n léèrè pé, “Àwòrán ati àkọlé ta ni ti ara rẹ̀ yìí?”Wọ́n ní, “Ti Kesari ni.”

25 Ó bá wí fún wọn pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari, kí ẹ sì fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Ọlọrun fún Ọlọrun.”

26 Wọn kò lè mú ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu lójú gbogbo eniyan. Ìdáhùn rẹ̀ yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n bá dákẹ́.

Ìbéèrè nípa Ajinde Òkú

27 Àwọn kan ninu àwọn Sadusi bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. (Àwọn Sadusi ni wọn kò gbà pé òkú kan a tún máa jinde.) Wọ́n bi í pé,

28 “Olùkọ́ni, Mose pàṣẹ fún wa pé bí eniyan bá ní iyawo, bí ó bá kú láìní ọmọ, kí àbúrò rẹ̀ ṣú iyawo rẹ̀ lópó, kí ó ní ọmọ lórúkọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

29 Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meje kan wà. Ekinni gbé iyawo, ó kú láìní ọmọ.

30 Bẹ́ẹ̀ náà ni ekeji.

31 Ẹkẹta náà ṣú u lópó. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mejeeje ṣe, wọ́n kú láì ní ọmọ.

32 Ní ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín, obinrin náà alára wá kú.

33 Ní ọjọ́ ajinde, ti ta ni obinrin náà yóo jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn mejeeje ló ti fi ṣe aya?”

34 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn eniyan ayé yìí ni wọ́n ń gbeyawo, tí wọn ń fi ọmọ fọ́kọ.

35 Ṣugbọn àwọn tí a kà yẹ fún ayé tí ó ń bọ̀, nígbà tí àwọn òkú bá jinde, kò ní máa gbeyawo, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní máa fọmọ fọ́kọ.

36 Nítorí wọn kò lè kú mọ́, nítorí bákan náà ni wọ́n rí pẹlu àwọn angẹli. Ọmọ Ọlọrun ni wọ́n, nítorí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ajinde.

37 Ó dájú pé a jí àwọn òkú dìde nítorí ohun tí Mose kọ ninu ìtàn ìgbẹ́ tí ń jóná, nígbà tí ó sọ pé, ‘Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun ti Jakọbu.’

38 Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú, ti àwọn alààyè ni; nítorí pé gbogbo wọn ni ó wà láàyè fún Ọlọrun.”

39 Àwọn kan ninu àwọn amòfin dá a lóhùn pé, “Olùkọ́ni, o wí ire!”

40 Láti ìgbà náà kò tún sí ẹni tí ó láyà láti bi í ní nǹkankan mọ́.

Ìbéèrè Nípa Ọmọ Dafidi

41 Jesu bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni wọ́n ṣe ń pe Mesaya ní ọmọ Dafidi?

42 Nítorí Dafidi sọ ninu ìwé Orin Dafidi pé,‘Oluwa wí fún oluwa mi pé:Jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún mi

43 títí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.’

44 Nígbà tí Dafidi pè é ní Oluwa, báwo ni ó ti ṣe tún jẹ́ ọmọ rẹ̀?”

Jesu Bá Àwọn Amòfin Wí

45 Ní etí gbogbo àwọn eniyan, Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,

46 “Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn amòfin tí wọ́n fẹ́ máa wọ agbádá ńlá. Wọ́n tún gbádùn kí eniyan máa kí wọn ní ààrin ọjà. Wọ́n fẹ́ràn láti jókòó níwájú ninu ilé ìpàdé ati láti jókòó ní ipò ọlá níbi àsè.

47 Wọn a máa jẹ ilé àwọn opó run. Wọ́n a máa gba adura gígùn láti ṣe àṣehàn. Wọn yóo gba ìdájọ́ líle.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24