1 Jesu pa òwe kan fún wọn láti kọ́ wọn pé eniyan gbọdọ̀ máa gbadura nígbà gbogbo, láì ṣàárẹ̀.
2 Ó ní, “Adájọ́ kan wà ní ìlú kan tí kò bẹ̀rù Ọlọrun, tí kò sì ka ẹnikẹ́ni sí.
3 Opó kan wà ninu ìlú náà tíí máa lọ sí ọ̀dọ̀ adájọ́ yìí tíí máa bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Ṣe ẹ̀tọ́ fún mi nípa ọ̀rọ̀ tí ó wà láàrin èmi ati ọ̀tá mi.’
4 Ọjọ́ ń gorí ọjọ́, sibẹ adájọ́ yìí kò fẹ́ ṣe nǹkankan nípa ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tí ó pẹ́, ó wá bá ara rẹ̀ sọ pé, ‘Bí n kò tilẹ̀ bìkítà fún ẹnikẹ́ni, ìbáà ṣe Ọlọrun tabi eniyan,
5 ṣugbọn nítorí opó yìí ń yọ mí lẹ́nu, n óo ṣe ẹ̀tọ́ fún un, kí ó má baà fi wahala rẹ̀ da mí lágara!’ ”
6 Oluwa wá sọ pé, “Ẹ kò gbọ́ ohun tí adájọ́ alaiṣootọ yìí wí!
7 Ǹjẹ́ Ọlọrun kò ní ṣe ẹ̀tọ́ nípa àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí wọn ń pè é lọ́sàn-án ati lóru? Ǹjẹ́ kò ní tètè dá wọn lóhùn?
8 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé yóo ṣe ẹ̀tọ́ fún wọn kíákíá. Ǹjẹ́ nígbà tí Ọmọ-Eniyan bá dé, yóo bá igbagbọ ní ayé mọ́?”
9 Ó wá pa òwe yìí fún àwọn tí wọ́n gbójú lé ara wọn bí olódodo, tí wọn ń kẹ́gàn gbogbo àwọn eniyan yòókù.
10 Ó ní, “Àwọn ọkunrin meji kan gòkè lọ sí Tẹmpili wọ́n lọ gbadura. Ọ̀kan jẹ́ Farisi, ekeji jẹ́ agbowó-odè.
11 “Èyí Farisi dá dúró, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura pé, ‘Ọlọrun, mo dúpẹ́ pé ń kò dàbí àwọn yòókù, àwọn oníwọ̀ra, alaiṣootọ, alágbèrè. N kò tilẹ̀ dàbí agbowó-odè yìí.
12 Ẹẹmeji ni mò ń gbààwẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Mò ń dá ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan tí mo bá gbà.’
13 “Ṣugbọn èyí agbowó-odè dúró ní òkèèrè. Kò tilẹ̀ gbé ojú sókè. Ó bá ń lu ara rẹ̀ láyà (bí àmì ìdárò), ó ní, ‘Ọlọrun ṣàánú mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀.’
14 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé agbowó-odè yìí lọ sí ilé rẹ̀ pẹlu ọkàn ìdáláre ju èyí Farisi lọ. Nítorí ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀; ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.”
15 Àwọn eniyan ń gbé àwọn ọmọ-ọwọ́ wá, pé kí ó lè fi ọwọ́ kàn wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn tí wọ́n gbé wọn wá wí.
16 Ṣugbọn Jesu pè wọ́n, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má dá wọn dúró, nítorí irú wọn ni ìjọba Ọlọrun.
17 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí kò bá gba ìjọba Ọlọrun bí ọmọde, kò ní wọ inú rẹ̀.”
18 Ìjòyè kan bi Jesu léèrè pé, “Olùkọ́ni rere, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”
19 Jesu sọ fún un pé, “Ìdí rẹ̀ tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kan àfi Ọlọrun nìkan ṣoṣo.
20 Ṣé o mọ òfin wọnyi: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè; ìwọ kò gbọdọ̀ paniyan; ìwọ kò gbọdọ̀ jalè; ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké; bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ.’ ”
21 Ìjòyè náà dáhùn pé, “Gbogbo òfin wọnyi ni mo ti ń pamọ́ láti ìgbà tí mo ti wà ní ọdọmọkunrin.”
22 Nígbà tí Jesu gbọ́, ó sọ fún un pé, “Nǹkankan ló kù ọ́ kù. Lọ ta gbogbo ohun tí o ní, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka, ìwọ yóo wá ní ìṣúra ní ọ̀run. Kí o máa wá tọ̀ mí lẹ́yìn.”
23 Nígbà tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú rẹ̀ bàjẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ pupọ.
24 Nígbà tí Jesu rí bí inú rẹ̀ ti bàjẹ́, ó ní, “Yóo ṣòro fún àwọn olówó láti wọ ìjọba Ọlọrun.
25 Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá, jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun.”
26 Àwọn tí ó gbọ́ ní, “Ta wá ni a óo gbà là?”
27 Ó dáhùn pé, “Ohun tí kò ṣeéṣe fún eniyan, ó ṣeéṣe fún Ọlọrun.”
28 Peteru sọ fún un pé, “Wò ó ná! Àwa ti fi ohun gbogbo tí a ní sílẹ̀, a sì ti ń tẹ̀lé ọ.”
29 Ó bá sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé kò sí ẹni tí ó fi ilé, iyawo, arakunrin, òbí tabi ọmọ sílẹ̀, nítorí ti ìjọba Ọlọrun,
30 tí kò ní rí ìlọ́po-ìlọ́po gbà ní ayé yìí, yóo sì ní ìyè ainipẹkun ní ayé tí ń bọ̀.”
31 Ó mú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila lọ sápá kan, ó sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí Jerusalẹmu tí à ń gòkè lọ yìí, gbogbo ohun tí àwọn wolii kọ nípa Ọmọ-Eniyan ni yóo ṣẹ.
32 Nítorí a óo fi í lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́. Wọn óo fi ṣe ẹ̀sín, wọn óo fi àbùkù kàn án, wọn óo tutọ́ sí i lára.
33 Nígbà tí wọ́n bá nà án tán, wọn óo sì pa á. Ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta, yóo jí dìde.”
34 Ṣugbọn ohun tí ó sọ kò yé wọn. Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà sápamọ́ fún wọn. Wọn kò mọ ohun tí ó ń sọ.
35 Nígbà tí Jesu súnmọ́ etí ìlú Jẹriko, afọ́jú kan wà lẹ́bàá ọ̀nà, ó jókòó, ó ń ṣagbe.
36 Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ eniyan ń kọjá lọ, ó wádìí ohun tí ó dé.
37 Wọ́n sọ fún un pé, “Jesu ará Nasarẹti ní ń kọjá.”
38 Ni alágbe náà bá pariwo pé, “Jesu, ọmọ Dafidi, ṣàánú mi!”
39 Àwọn tí ó ń kọjá lọ ń bá a wí pé kí ó panu mọ́. Ṣugbọn ńṣe ni ó túbọ̀ ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú mi.”
40 Jesu bá dúró, ó ní kí wọ́n lọ fà á lọ́wọ́ wá sọ́dọ̀ òun. Nígbà tí ó dé, Jesu bi í pé,
41 “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ?”Ó dáhùn pé, “Alàgbà, mo fẹ́ tún ríran ni!”
42 Jesu sọ fún un pé, “Ǹjẹ́, ríran. Igbagbọ rẹ mú ọ lára dá.”
43 Lójú kan náà ó sì tún ríran, ó bá ń tẹ̀lé Jesu, ó ń yin Ọlọrun lógo. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọrun.