Maku 16 BM

Ajinde Jesu

1 Lẹ́yìn tí Ọjọ́ Ìsinmi ti kọjá, Maria Magidaleni ati Maria ìyá Jakọbu ati Salomi ra òróró ìkunra, wọ́n fẹ́ lọ fi kun òkú Jesu.

2 Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, wọ́n dé ibojì bí oòrùn ti ń yọ.

3-4 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn ṣàròyé pé, “Ta ni yóo bá wa yí òkúta kúrò ní ẹnu ibojì?” Bí wọ́n ti gbé ojú sókè, wọ́n rí i pé ẹnìkan ti yí òkúta náà kúrò, bẹ́ẹ̀ ni òkúta ọ̀hún sì tóbi gan-an.

5 Nígbà tí wọ́n wo inú ibojì, wọ́n rí ọdọmọkunrin kan tí ó jókòó ní apá ọ̀tún wọn, tí ó wọ aṣọ funfun. Wọ́n bá ta gìrì.

6 Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ṣé Jesu ará Nasarẹti tí a kàn mọ́ agbelebu ni ẹ̀ ń wá? Ó ti jí dìde. Kò sí níhìn-ín. Ẹ wò ó! Ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí nìyí.

7 Ṣugbọn ẹ lọ, ẹ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati Peteru pé ó ti lọ ṣáájú yín sí Galili, níbẹ̀ ni ẹ óo gbé rí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fun yín.”

8 Nígbà tí wọ́n jáde, aré ni wọ́n sá kúrò ní ibojì náà, nítorí ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, tí wọn ń dààmú. Wọn kò sọ ohunkohun fún ẹnikẹ́ni, nítorí ẹ̀rù ń bà wọ́n.[

9 Àwọn obinrin náà sọ ohun gbogbo tí a rán wọn fún Peteru ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ṣókí.

10 Lẹ́yìn èyí, Jesu fúnrarẹ̀ rán wọn lọ jákèjádò ayé láti kéde ìyìn rere ìgbàlà ayérayé, ìyìn rere tí ó ní ọ̀wọ̀, tí kò sì lè díbàjẹ́ lae.][

(ÌPARÍ ÌYÌN RERE NÍ ṢÓKÍ)

(ÌPARÍ ÌYÌN RERE TÍ Ó GÙN)

Jesu Fara han Maria Magidaleni

9 Nígbà tí Jesu jí dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, ó kọ́ fara han Maria Magidaleni, tí Jesu lé ẹ̀mí èṣù meje kúrò ninu rẹ̀ nígbà kan.

10 Ó lọ sọ fún àwọn tí ó ti ń bá Jesu gbé níbi tí wọn ti ń ṣọ̀fọ̀, tí wọn ń sunkún.

11 Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jesu wà láàyè ati pé Maria ti rí i, wọn kò gbàgbọ́.

Jesu Fara Han Àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn Meji

12 Lẹ́yìn náà, ó fara han àwọn meji kan ninu wọn ní ọ̀nà mìíràn, bí wọ́n ti ń rìn lọ sí ìgbèríko kan.

13 Wọ́n bá pada lọ ròyìn fún àwọn ìyókù. Sibẹ wọn kò gbàgbọ́.

Jesu Fara Han Àwọn Mọkanla

14 Lẹ́yìn náà ó fara han àwọn mọkanla bí wọ́n ti ń jẹun. Ó bá wọn wí fún aigbagbọ ati ọkàn líle wọn, nítorí wọn kò gba àwọn tí wọ́n rí i, tí wọ́n sọ pé ó ti jinde gbọ́.

15 Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ máa waasu ìyìn rere fún gbogbo ẹ̀dá.

16 Ẹni tí ó bá gbàgbọ́, tí ó bá ṣe ìrìbọmi, yóo ní ìgbàlà. Ẹni tí kò bá gbàgbọ́ yóo gba ìdálẹ́bi.

17 Àwọn àmì tí yóo máa bá àwọn tí ó gbàgbọ́ lọ nìwọ̀nyí; wọn yóo máa lé ẹ̀mí burúkú jáde ní orúkọ mi; wọn yóo máa fi àwọn èdè titun sọ̀rọ̀;

18 wọn yóo gbé ejò lọ́wọ́, wọn yóo mu òògùn olóró, ṣugbọn kò ní ṣe wọ́n léṣe; wọn yóo gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn, ara wọn yóo sì dá.”

Ìgòkè-Re-Ọ̀run Ti Jesu

19 Lẹ́yìn tí Jesu Oluwa ti bá wọn sọ̀rọ̀ tán, a gbé e lọ sí òkè ọ̀run, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun.

20 Nígbà tí wọ́n túká lọ, wọ́n ń waasu ní ibi gbogbo, Oluwa ń bá wọ́n ṣiṣẹ́, ó ń fi ìdí ọ̀rọ̀ ìyìn rere múlẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ àmì tí ó ń bá wọn lọ.]

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16