Maku 6 BM

A Kọ Jesu ní Nasarẹti

1 Jesu jáde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ìlú rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá a lọ.

2 Nígbà tí ó di Ọjọ́ Ìsinmi, ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé. Ẹnu ya ọpọlọpọ àwọn tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀. Wọ́n ń wí pé, “Níbo ni eléyìí ti kọ́ ẹ̀kọ́? Irú ọgbọ́n wo ni ọgbọ́n tirẹ̀ yìí, tí iṣẹ́ ìyanu ń ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe?

3 Ṣebí gbẹ́nàgbẹ́nà ni, ọmọ Maria, arakunrin Jakọbu, ati Juda, ati Simoni? Ṣebí àwọn arabinrin rẹ̀ nìwọ̀nyí lọ́dọ̀ wa yìí?” Wọ́n sì kọ̀ ọ́.

4 Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Kò sí wolii tí kò níyì, àfi ní ìlú ara rẹ̀, ati láàrin àwọn ará rẹ̀, ati ninu ẹbí rẹ̀.”

5 Kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu níbẹ̀ àfi pé ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé àwọn aláìsàn bíi mélòó kan, a sì wò wọ́n sàn.

6 Ẹnu yà á nítorí aigbagbọ wọn.Jesu ń káàkiri gbogbo àwọn abúlé tí ó wà yíká, ó ń kọ́ àwọn eniyan.

Jesu Rán Àwọn Mejila Níṣẹ́

7 Ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila, ó rán wọn lọ ní meji-meji, ó fi àṣẹ fún wọn lórí àwọn ẹ̀mí èṣù.

8 Ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn má mú ohunkohun lọ́wọ́ ní ọ̀nà àjò náà àfi ọ̀pá nìkan. Wọn kò gbọdọ̀ mú oúnjẹ, tabi igbá báárà lọ́wọ́, tabi kí wọn fi owó sinu àpò wọn.

9 Kí wọn wọ bàtà, ṣugbọn kí wọn má wọ ẹ̀wù meji.

10 Ó tún fi kún un fún wọn pé, “Ilékílé tí ẹ bá wọ̀, níbẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò ní ìlú náà.

11 Ibikíbi tí wọn kò bá ti gbà yín, tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ yín, ẹ jáde kúrò níbẹ̀, kí ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí láti kìlọ̀ fún wọn.”

12 Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ti ń lọ, wọ́n ń waasu pé kí gbogbo eniyan ronupiwada.

13 Wọ́n ń lé ọpọlọpọ ẹ̀mí èṣù jáde, wọ́n ń fi òróró pa ọpọlọpọ aláìsàn lára, wọ́n sì ń mú wọn lára dá.

Ikú Johanu Onítẹ̀bọmi

14 Hẹrọdu ọba gbọ́ nípa Jesu, nítorí òkìkí rẹ̀ kàn. Àwọn kan ń sọ pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó jí dìde ninu òkú, òun ni ó jẹ́ kí ó lè máa ṣe iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀.”

15 Ṣugbọn àwọn mìíràn ń wí pé, “Elija ni.”Àwọnmìíràn ní, “Wolii ni, bí ọ̀kan ninu àwọn wolii àtijọ́.”

16 Ṣugbọn nígbà tí Hẹrọdu gbọ́, ó ní, “Johanu tí mo ti bẹ́ lórí ni ó jí dìde.”

17 Nítorí Hẹrọdu kan náà yìí ni ó ranṣẹ lọ mú Johanu tí ó fi í sẹ́wọ̀n nítorí ọ̀ràn Hẹrọdiasi iyawo Filipi arakunrin Hẹrọdu tí Hẹrọdu gbà.

18 Nítorí Johanu a máa wí fún Hẹrọdu pé, “Kò yẹ fún ọ láti gba iyawo arakunrin rẹ.”

19 Nítorí náà Hẹrọdiasi ní Johanu sinu, ó fẹ́ pa á, ṣugbọn kò lè pa á,

20 nítorí Hẹrọdu bẹ̀rù Johanu, nítorí ó mọ̀ pé olóòótọ́ eniyan ni ati pé kò ní àléébù. Nítorí náà ó dáàbò bò ó. Ọkàn Hẹrọdu a máa dàrú gidigidi nígbàkúùgbà tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, sibẹ a máa fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

21 Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, Hẹrọdiasi rí àkókò tí ó wọ̀ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Hẹrọdu se àsè ọjọ́ ìbí rẹ̀, ó pe àwọn ìjòyè, àwọn ọ̀gágun, ati àwọn eniyan pataki ilẹ̀ Galili.

22 Ọmọ Hẹrọdiasi obinrin bá wọlé, ó bọ́ sí agbo, ó bẹ̀rẹ̀ sí jó, inú Hẹrọdu ati ti àwọn tí ó wà níbi àsè náà dùn. Ọba sọ fún ọmọbinrin náà pé, “Bèèrè ohun tí o bá fẹ́, n óo fi í fún ọ.”

23 Ó bá búra fún un pé, “N óo fún ọ ní ohunkohun tí o bá bèèrè, kì báà ṣe ìdajì ìjọba mi.”

24 Ọmọbinrin náà bá lọ sí ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ó ní, “Kí ni kí n bèèrè?”Ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Bèèrè orí Johanu Onítẹ̀bọmi.”

25 Ọmọbinrin náà yára lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, ó wí pé, “Mo fẹ́ kí o fún mi ní orí Johanu Onítẹ̀bọmi kíákíá, kí wọ́n fi àwo pẹrẹsẹ gbé e wá.”

26 Inú ọba bàjẹ́ pupọ, ṣugbọn nítorí ó ti ṣe ìlérí pẹlu ìbúra lójú àwọn tí ó wà níbi àsè, kò fẹ́ kọ̀ fún un.

27 Lẹsẹkẹsẹ ọba rán ọmọ-ogun kan, ó pàṣẹ fún un kí ó gbé orí Johanu wá. Ó bá lọ, ó bẹ́ ẹ lórí ninu ilé ẹ̀wọ̀n.

28 Ó bá fi àwo pẹrẹsẹ gbé orí rẹ̀ wá, ó fi í fún ọmọbinrin náà. Ọmọbinrin náà bá gbé e lọ fún ìyá rẹ̀.

29 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu gbọ́, wọ́n wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n sin ín sinu ibojì.

Jesu Bọ́ Ẹgbẹẹdọgbọn (5,000) Eniyan

30 Àwọn aposteli Jesu pé jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ròyìn gbogbo nǹkan tí wọ́n ti ṣe ati bí wọ́n ti kọ́ àwọn eniyan.

31 Ó bá wí fún wọn pé, “Ẹ wá kí á lọ sí ibìkan níkọ̀kọ̀, níbi tí kò sí eniyan, kí ẹ sinmi díẹ̀.” Nítorí ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n ń lọ, tí wọn ń bọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi sí àyè láti jẹun.

32 Wọ́n bá bọ́ sinu ọkọ̀ ojú omi kan, wọ́n fẹ́ yọ́ lọ sí ibi tí kò sí eniyan.

33 Ṣugbọn ọpọlọpọ eniyan rí wọn bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n mọ̀ wọ́n, wọ́n bá fi ẹsẹ̀ rìn, wọ́n sáré láti inú gbogbo ìlú wọn lọ sí ibi tí ọkọ̀ darí sí, wọ́n sì ṣáájú wọn dé ibẹ̀.

34 Nígbà tí Jesu jáde ninu ọkọ̀ ó rí ọpọlọpọ eniyan, àánú ṣe é nítorí wọ́n dàbí aguntan tí kò ní olùṣọ́. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ọpọlọpọ nǹkan.

35 Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, wọ́n wí fún un pé, “Aṣálẹ̀ nìhín yìí, ilẹ̀ sì ń ṣú lọ.

36 Jẹ́ kí àwọn eniyan túká, kí wọn lè lọ sí àwọn abà ati abúlé tí ó wà yíká láti ra oúnjẹ fún ara wọn.”

37 Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni kí ẹ fún wọn ní ohun tí wọn óo jẹ.”Wọ́n ní, “Ṣé kí á wá lọ ra oúnjẹ igba owó fadaka ni, kí a lè fún wọn jẹ!”

38 Ó bi wọ́n pé, “Ìba oúnjẹ wo ni ẹ ní? Ẹ lọ wò ó.”Lẹ́yìn tí wọ́n wádìí, wọ́n ní “Burẹdi marun-un ni ati ẹja meji.”

39 Ó bá pàṣẹ fún wọn kí gbogbo àwọn eniyan jókòó ní ìṣọ̀wọ́, ìṣọ̀wọ́ lórí koríko.

40 Wọ́n bá jókòó lọ́wọ̀ọ̀wọ́, ní ọgọọgọrun-un ati ní aadọtọọta.

41 Jesu bá mú burẹdi marun-un ati ẹja meji náà, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó dúpẹ́. Ó bá bu burẹdi náà, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọn pín in fún àwọn eniyan. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó pín ẹja meji náà fún gbogbo wọn.

42 Gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó.

43 Wọ́n bá kó àjẹkù burẹdi ati ẹja jọ, ó kún agbọ̀n mejila.

44 Iye àwọn ọkunrin tí ó jẹ oúnjẹ náà jẹ́ ẹgbẹẹdọgbọn (5000).

Jesu Rìn lórí Omi

45 Lẹsẹkẹsẹ ó ní kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi, kí wọn ṣiwaju rẹ̀ lọ sí òdìkejì òkun ní agbègbè Bẹtisaida. Lẹ́yìn náà ó ní kí àwọn eniyan túká.

46 Nígbà tí ó ti dágbére fún wọn, ó lọ sí orí òkè, ó lọ gbadura.

47 Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà ninu ọkọ̀ ní ààrin òkun, òun nìkan ni ó kù lórí ilẹ̀.

48 Ó rí i pé pẹlu ipá ni wọ́n fi ń wa ọkọ̀, nítorí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì sí wọn. Ó tó bí agogo mẹta òru kí Jesu tó máa lọ sọ́dọ̀ wọn. Ó ń rìn lórí omi, ó fẹ́ kọjá lára wọn.

49 Nígbà tí wọn rí i tí ó ń rìn lórí omi, wọ́n ṣebí iwin ni, wọ́n bá kígbe.

50 Nítorí gbogbo wọn ni wọ́n rí i tí ẹ̀rù sì bà wọ́n.Ṣugbọn lójú kan náà ó fọhùn sí wọn, ó ní, “Ẹ fi ọkàn balẹ̀. Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù.”

51 Ó bá wọ inú ọkọ̀ tọ̀ wọ́n lọ, afẹ́fẹ́ bá rọlẹ̀. Ẹnu yà wọ́n lọpọlọpọ,

52 nítorí pé iṣẹ́ ìyanu ti burẹdi kò yé wọn, nítorí òpè ni wọ́n.

Jesu Wo Ọ̀pọ̀ Eniyan Sàn ní Genesarẹti

53 Nígbà tí wọ́n la òkun já, wọ́n dé Genesarẹti, wọ́n bá gúnlẹ̀.

54 Bí wọ́n ti jáde kúrò ninu ọkọ̀, lẹsẹkẹsẹ àwọn eniyan mọ̀ wọ́n.

55 Wọ́n bá ń súré láti gbogbo àdúgbò ibẹ̀, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn wọn lórí ibùsùn wá sí ibikíbi tí wọn bá gbọ́ pé Jesu wà.

56 Níbikíbi tí ó bá wọ̀, ìbáà ṣe ní abúlé tabi ninu ìlú, ní ìgbèríko, tabi ní ọjà, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn wá. Wọn a máa bẹ̀ ẹ́ pé kí wọn ṣá lè fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí ẹ̀wù rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ kàn án pátá ni ó mú lára dá.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16